Adekunle Rufai gbakoso egbe oselu AA pada - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 6 November 2022

Adekunle Rufai gbakoso egbe oselu AA pada



Ile ejo giga tijoba apapo to wa niluu Abuja, ti pase pe ki ajo eleto idibo lorileede yii iyen INEC, fagile Ogagun Hamza Al Mustapha gege bi oludije aare fegbe oselu Action Alliance(AA).

Iyen nikan ko bee ni won tun fagile gbogbo oruko ti iko Kenneth Udeze, fi sowo si won, nitori won ko gba a lona eto.

Bakan naa ni Adajo Z B Abubakar, to gbe Idajo naa kale tun pase pe ki ajo INEC, yara tete gbe oruko awon oludije ti alaga egbe yii, Alaaji Adekunl Rufai Omoaje fowo si jade nitori awon gan-an ni ojulowo.

Gege bi a se gbo, Alaaji Rufai Omo Aje,to je alaga egbe naa lo gba Ile ejo lo loruko egbe oselu AA, nibi to ti ro won lati je ki ajo eleto idibo INEC, gba awon oludije e gege bi ojulowo

 Pelu bi nnkan se n lọ yii o see se ki Al Mustapha padanu ipo e gege bi oludije aare fegbe oselu AA, ko si je pe oruko eni ti alaga won, Omoaje ba fa kale ni yoo je oludije won.

Bee loro naa kan gbogbo awon oludije lati ori seneto, asoju-sofin,gomina atawon omo Ile igbimo asofin ti Kenneth Udeze fi sowo si ajo INEC.


Bi oro se wa ri bayii, o ti fihan pe alaga egbe naa Adekunle Omoaje ti gba akoso e pada, odo e si ni awon oludije gbogbo ti yoo kopa ninu ibo labe egbe oselu AA yoo ti jade.


Ninu oro e, Adekunle Omoaje, alaga egbe naa lapapo ti fi idunnu e han si ase Ile ejo naa, o so pe Kenneth Udeze, to n pe ara e ni alaga lo je pe lati odun 2020, ni won ti le e danu nibi ipade gbogbogbo egbe to waye niluu Osogbo.


No comments:

Post a Comment

Pages