Aṣaaju ẹgbẹ oṣelu NNPP nipinlẹ Ọyọ, to tun ti figba kan jẹ agba ẹgbẹ PDP, Alaaji AbdulRashed Adebisi tọpọ awọn eeyan mọ si Ọlọpọeeyan ti sọ pe ko saaye fun Gomina Ṣeyi Makinde, lati wọle pada si ipo gomina lẹẹkeji, ninu ibo to n bọ lọdun 2023, nitori ọdun mẹrin pere ni yoo lo.
Ọkunrin naa sọrọ yii lakooko to n bawọn oniroyin sọrọ niluu Ibadan, o sọ pe ko si nnkan to ku fun Gomina ọhun ju pe to ba pari saa ọdun mẹrin to n lo yii ko pada sile ẹ nitori gbogbo eyi to wọn nawọ meji soke yẹn o kan fi n tan ara ẹ jẹ ni.
O ni oun dupẹ lọwọ Ọlọrun pe o da ija silẹ laarin oun ati Gomina naa, to ni kawọn fẹgbẹ PDP ọhun silẹ fun-un, nitori gbogbo awọn to n tẹle e niya n jẹ, ti ki i ṣe kekere, ti ko si si apẹẹrẹ pe wọn wa nijọba lara wọn.
Agba oṣelu naa tun fikun un ninu ọrọ ẹ pe ka ni Ṣeyi Makinde ṣe daadaa fawọn to ran an lọwọ paapaa oun toun lọ ba a pe ko wa dije fun gomina lẹyin to ti ro ara ẹ pin pe oun ko ṣe mọ ni awọn ko ni fẹgbẹ naa silẹ.
O sọ pe, ‘’ Emi nikan kọ ni mo fi ẹgbẹ naa silẹ, awa kan lọ si NNPP nigba tawọn kan lọ si SDP, to ba jẹ pe emi nikan ni mo n ja lori nnkankan, ko yẹ kawọn yooku naa kuro nibẹ. O tumọ si pe Ṣeyi Makinde funra rẹ ni ko dara niyẹn, ka ni o dara ni, a ko le pọ ka a kuro, awọn kan lọ si APC. Ko si nnkankan to faa ju pe ko ni ọwọ ni. Ki Ọlọrun fọrunkẹ Gomina Akala, ki i ṣe pe nigba to wa nibẹ, o ko owo fẹnikankan, rara o, ṣugbọn wọn mọ riri eeyan pe awọn eeyan awọn ni eleyii.
Nigba ti Akala wa nijọba ko sẹni ti ko ta apọnle fun, ẹni ti ko to nnkan, o jẹ ko mọ pe o to mẹwaa, oun ni gbogbo ẹ, awọn nnkan ti ọpọlọpọ eeyan n reti niyẹn, Iru nnkan ta a n ṣe to dija yii pe ko mojuto awọn ọmọ ẹgbẹ, nnkan teeyan le fi mojuto ọmọ ẹgbẹ ki i ṣe owo, elo ni Gomina fẹẹ fun ẹnikọọkan to le too jẹ’’.
Bẹẹ ni Alaaji Adebisi tun fi aidunnu ẹ han lori ọrọ ti Ṣeyin Makinde sọ lori eto ori redio laipẹ yii pe oun fawọn ijọba ibilẹ ni miliọnu mẹwaa tẹlẹ, amọ nigba toun ko mọ bi wọn ṣe n ṣe e, oun ko fun wọn mọ.
O ni, ‘’ Ṣebi o yẹ ko pe awọn alaga ijọba ibilẹ naa pe iye bayii ni, ati pe ṣe miliọnu mẹwaa naira lowo wọn loṣooṣu, kin ni nnkan to ran, koda o sọ pe oun ni ki wọn maa fawọn ọlọpaa lowo, bẹẹẹ si beeere lọwọ wọn, wọn a sọ pe wọn ko fawọn ni kọbọ, emi o gbagbọ ninu gbogbo yẹn.’’
‘’Ati pe Gomina wa n parọ ni, ṣe ẹ fẹ sọ pe Ṣeyi Makinde, ko mọ pe oun parọ lọjọ to n bawọn araalu sọrọ, o mọ amọ nitori o jẹ gomina, awọn to wa labẹ ẹ ko ni i sọ fun, ka ni emi ni mo fọrọ waa lẹnu wo, ma sọ pe irọ lo n pa, nitori pe emi mọ. Oun ti mo sọ ni pe miliọnu mẹwaa to ni kawọn ijọba ibilẹ ma gba loṣooṣu, owo kin ni?.Awọn gbogbo nnkan bẹẹ bigba ti eeyan nika ninu ni mo ka a si’’.
Lori ahesọ ọrọ kan pe ipo alaga garaaji lo da wahala silẹ, agba oloṣelu naa sọ pe ṣe oun jọ ọmọ ẹgbẹ garaji ni? Ati pe kin ni oun fẹẹ fipo naa ṣe, ko wu oun laelae, adura oun si ni pe ki Ọlọrun ma jẹ ki iran oun de idi ẹ. Bawo wa ni toun ṣe jẹ nigba to oun nigba ti oun ki i ṣe dẹrẹba, o lawọn ti wọn sọ yẹn, isọkunsọ ni wọn sọ nitori bi wọn ṣe le ro iru nnkan bẹẹ si oun ko ye oun, ọpọ awọn to si n sọ loun ko mọ wọn.
Ọkunrin yii waa sọ pẹlu idailoju pe ẹgbẹ oṣelu NNPP, ni yoo wọle fun ipo gomina lọdun to n bọ. Idi ni pe gẹgẹ bo ṣe wi, PDP to wa lori aleefa yii nigba tawọn bẹrẹ ko to nnkan to wa ninu NNPP bayii. O nitori ko si ẹnikankan nibẹ mọ, ko to di pe awọn papọ.
Ọlọpọeeyan ni nigba tawọn Ladọja tun lọ, ibẹ tun fuyẹ amọ nigba ti Ọlọrun ma gbe iṣe ẹ de, wọn pada, o ni nnkan toun sọ ni pe ko si ẹgbẹ kan ti ko le wọle. Bẹẹ lo ni o yẹ ki wọn ti le Ṣeyi Makinde kuro ninu ẹgbẹ PDP, nitori igbesẹ to n gbe lori ọrọ Atiku.
O ni, ‘’ Oṣelu buruku ni, ninu ẹgbẹ teeyan wa, ko sọ pe oun ko ni ṣatilẹyin fun aarẹ oun.Ohun to ya mi lẹnu lori ọrọ ẹ ni pe nnkan to fi lọ awa, ko fẹẹ ki wọn fi lọ oun, ṣebi nigba ta a wa nibẹ, bo ṣe ran kanakan mọ niyii, awa o ṣe ni ki alaga ẹ kọwe fipo silẹ,ohun to fi ṣe wa ti awa fi kuro ni Ọlọrun fi ṣe ẹsan fun un.
Gbogbo nnkan to n sọ yẹn, awọn ọmọ ẹgbẹ ẹ ko ni gba o, ṣe awọn ti wọn fun ni tikẹẹti yoo sọ pe oun ko ni dibo mọ, irọ ni gbogbo ẹ, ẹnu ori redio lasan ni.Ṣeyi Makinde ko lagbara kankan lori pe Atiku yoo wọle tabi ko nii wọle.
Onikaluku lo ti mọ ẹni ti yoo dibo ẹ fun, ẹni to yẹ ki wọn ti le danu ninu ẹgbẹ ni, ka ni emi ni Atiku ni. Nitori ibajẹ eeyan wọn ko da iṣẹ Ọlọrun duro’’
No comments:
Post a Comment