Ọla ni wọn yoo ṣe ifilọlẹ fiimu Yara Ikọkọ - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 5 November 2022

Ọla ni wọn yoo ṣe ifilọlẹ fiimu Yara Ikọkọ


Gbogbo eto lo ti to fun ifilọlẹ fiimu Yara Ikọkọ, ti Ajihinrere Olusọla Ṣowumi  Jibọla, tileeṣẹ iranṣẹ El-Shadai Evangelical Drama Ministry gbe jade, eyi ti yoo waye ni ọla, Ọjọ Aiku, ọjọ kẹfa, oṣu kọkanla, nile ijọsin God’s Speed Evangelical Penticostal Church, Adebẹsin lẹgbẹ ileeṣẹ burẹdi Orẹoluwa, Car- Wash, Adatan, niluu Abẹokuta.

Fiimu ọhun ti Ajihinrere Igbalade Peter Oluwasinaayọmi dari ẹ, ni wọn ti n reti awọn eeyan jakan jakan lọjọ naa. Nigba ti  Ajihinrere Adekọla Jethro Oyekanmi, yoo dari eto lọjọ naa. Fiimu Yara Ikọkọ, ni wọn lo kun fun imisi,to si tun aṣiri aye, nipa fifi adura jagun awọn ọmọ Ọlọrun.


No comments:

Post a Comment

Pages