Irọ ni wọn pa
Titi di akoko ta a wa yii, inu ibẹru bojo lawọn eeyan Ilawọ nijọba ibilẹ Ọdẹda, nipinlẹ Ogun, wa bayii, nitori bi wọn ṣe fẹsun kan ọba tuntun ti wọn ṣẹṣẹ darukọ ẹ, Ọba Alexander Oluṣẹgun Macgregor, pe o ko awọn tọọgi wọnu ilu naa, ti wọn si sa awọn eeyan yannayanna.
Bo tilẹ jẹ pe a gbọ pe ọwọ ọlọpaa Adatan, niluu Abẹokuta, ti tẹ marun-un, ninu awọn ti wọn ṣiṣẹ ọhun, ti wọn si ni wọn yoo foju bale ẹjọ sibẹ ṣe ni ọkan awọn ara abule ọhun ko balẹ, nitori wọn ni awọn ko mọ nnkan to tun le ṣẹlẹ.
‘’Ilu gbera lati lọ toju awọn ti wọn ṣa, lati bi ọjọ Monde, ni awọn eeyan Macgrgor, tun ti gbiyanju lati gba awọn ti wọn ṣiṣẹ ibi yẹn silẹ, nitori wọn mu marun-un, ninu wọn, bẹẹ ni wọn tun ti lọọ n bawọn ti ṣa pe ki wọn maa sẹjọ mọ amọ ọlọpaa Adatan, ko gba fun wọn, won ti gbe wọn lọ sile ẹjọ’’.
Ninu ọrọ Oloye Lawrence Lawrence Olufẹmi Atanda Ogunsanya, ọkan lara awọn oludije ọba niluu naa, o sọ pe, Nigba ti mo nifẹẹ lati jọba, mo wa si ilu, nitori pe awọn babanla wa, wa lara awọn to ja fun ominira Ẹgba nigba naa. Wọn ni ki n to le jẹ ọba , mo gbodọ ni awọtẹlẹ, ki lo n jẹ bẹẹ, wọn ni mo gbọdọ joye ilu ti wọn si foun jẹ Akọgun’’. ni lẹyin toun jẹ ẹ tan ni wọn sọ foun pe oun lẹtọọ lati dupo ọba, awọn marun-un lawọn gba fọọmu. Tawọn ilu si mu forukọ awọn afọbajẹ ti wọn yoo yan ọba si ijọba ibilẹ Ọdẹda, amọ siyalẹnu awọn, wọn to yọ orukọ awọn mẹfa kuro nibẹ ti wọn si forukọ mii-in rọpo ẹ. Ibẹ lo ni wahala ti kọkọ bẹrẹ.
‘’Ilu kọ lẹta si wọn pada pe orukọ tawọn kọ fun yin kọ ni ẹ da pada, nitori awọn to yẹ ki orukọ wọn yẹ ko wa nibẹ ko si nibẹ, ọjọ keji ti wọn kọ lẹta,la gbọ pe wọn fẹẹ ṣe ipade kan ni ẹlẹgun mẹfa, Eko ni mo wa lọjọ naa ti mo ranṣẹ sawọn eeyan mi lati lọ sibẹ, ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ pe nigba ti wọn debẹ ni wọn sọ pe ọba ni wọn fẹẹ yan.
‘’Macgregor nikan lo wa nibẹ, ipaya ko jẹ ko sọkalẹ ninu mọto,titi ti wọn fi pari, ko sọkalẹ. Ilu ni ile Ogboni ni wọn gbọdọ ti ṣe, awa oludije yooku, wọn ko kọ lẹta si wa, wọn ko pe wa, a ko mọ nnkankan nipa ẹ, gbogbo bi wọn ṣe ṣeto yẹn la ni akọsilẹ ẹ. Wọn ṣa ṣe awuruju lọjọ naa ti wọn sọ pe Macgregor lo wọle’’
Oloye Lawrence tun sọ pe ko si idile to n jọba ninu ilu naa amọ awọn baba wọn lo tẹ ilu naa do nitori nigba ti wọn n bọ lati ifẹ, wọn lọ si Ila Ọrangun, ọrọ ọba naa lo da ija silẹ laarin ẹgbọn ati aburo, tawọn kan fi ṣi lati ibẹ lọ si Odo-Ọna ni Ibadan, latibẹ ni wọn gba de inu igbo Ẹgba. Ṣugbọn ki wọn to debẹ abule kan wa ti wọn maa n pe ni ẹlẹgun mẹfa, oun ni wọn fi ṣe ibi ti wọn de si, amọ nigba ti wọn ko dagba soke ni wọn pada lọọ si Alagbaagba.
O ni pupọ ni awọn to di Orile-Ilawọ, Alagbaagba ni wọn wa, ibẹ ni ilu pọ si. Ibẹ ni wọn gba wọnu igbo Ẹgba, to fi jẹ pe Ilahọ jẹ ọkan ninu Ẹgba. Ninu ọrọ Ọba tuntun ti wọn ṣẹṣẹ yan ti wọn fẹsun kan iyẹn Ọba Oluṣẹgun Macgregor, lo ti sọ pe Oluwa lo yan oun lọba Ilawọ, iṣẹ Eledumare ti ko ṣee tu ni.
O sọ pe kawọn ti wọn n ta ẹjẹ eeyan silẹ nitori ipo ọba atawọn ti wọn n pe orukọ Macregor si ipaniyan lati yee ṣe bẹẹ. Ṣugbọn nnkan to daju ni pe ki wọn fọwọ sowọ pọ pẹlu oun lati gbe Ilawọ goke agba, ki wọn mu gbogbo ikunsinu to wa lọkan wọn kuro patapata, nitori rogbodiyan ki i ran ilu lọwọ, ifasẹyin ati orukọ buruku ni i mu ba ni.
O ni ” Awọn eeyan to mọ emi Ọjọgbọn Macgregor daadaa mọ pe ẹni alaafia ni mi, iṣesi mi gẹgẹ bi akọṣẹmọṣẹ ati araalu lasan ko tako alaafia ri, awọn eeyan to mọ mi nilẹ yii ati loke okun si le jẹri si i pe bo ṣe ri gan-an niyẹn’’
No comments:
Post a Comment