Ko si awitunwi kankan mọ pe Agbẹjọro Olubiyi ọmọ Ọtẹgbẹyẹ, ti jade patapata lai boju wẹyin, gẹgẹ bi oludije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress (ADC), iyẹn ẹgbẹ bọ mi lọwọ, ki n bọ ọ lọwọ, nipinlẹ Ogun.
Nigba ti iroyin kọkọ gbe e jade nigba naa pe ọkunrin jade dupo iyẹn nigba ti ajọ eleto idibo lorileede yii INEC, ko tii gbe orukọ oludije kankan jade, irọ ni awọn kan n pe e paapaa julọ awọn alatako oṣelu, ti wọn si n sọ pe ko le ribẹ.
Awọn kan ninu wọn tiẹ n sọ pe ajọ INEC, ko le gbe orukọ ẹ jade, idi niyii tawọn kan fi kọkọ gbe iroyin ẹlẹjẹ kan sita nigba kan pe orukọ Ọtẹgbẹyẹ ko si ninu eyi ti ajọ naa fẹẹ gbe jade, ti wọn si lẹ orukọ ti tẹlẹ jade lati fi pa awọn eeyan lẹnu mọ.
Ṣugbọn nigba to di ọjọ kẹrin, oṣu kẹwaa, ọdun yii, ni jẹbẹtẹ gbọmọ le awọn alatako oloṣelu yii lọwọ, nigba ti orukọ Biyi Ọtẹgbẹyẹ, jade gẹgẹ bi ojulowo oludije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu ADC, nipinlẹ Ogun. Latigba naa ni ara wọn ko balẹ mọ.
Eyi ko le ṣe ko ma ri bẹẹ, nitori ninu oṣu kẹsan-an, ọdun yii, ni Sẹnetọ Ibikunle Amosun, gomina tẹlẹ nipinlẹ Ogun, sọ nigbangba pe ko si pe a n fi nnkan bo ara wa loju ninu ọrọ ibo to n bọ yii, nitori Olubiyi Ọtẹgbẹyẹ, ti ẹgbẹ oṣelu ADC, loun yoo ṣiṣẹ fun gẹgẹ bi gomina fọdun 2023.
Ere ni, awada ni, wọn n pe ọrọ naa, amọ ni bayii, o ti wa fihan gbangba pe ara o rokun, ara ko rọ adiyẹ wọn mọ bayii, ti ọkan wọn ko si balẹ mọ tọrọ naa waa fẹẹ di igi ta a foju winna, to wa n wo pa wọn.
Gbogbo ọna lati ti Ọtẹgbẹyẹ ṣubu ni wọn n wa, amọ to jẹ pe Ọlọrun fi ye wọn pe, ẹni toun ba ti wa lẹyin ẹ, ko si nnkan ti ẹda alaye kan le ṣe fun-un. Boya lawọn eeyan mọ pe igba akọkọ kọ ree, ti ọkunrin yii yoo jade dupo oṣelu.
Bẹẹ ni igba akọkọ kọ, o ti jade dupo sẹnetọ ri bẹẹ naa ni aṣoju-ṣofin, ṣugbọn ti Ọlọrun sọ pe ki i ṣe ipo toun fẹ fun niyii, nitori Olodumare wa yii, o mọ nnkan to n ṣe ninu igbe aye ọmọ ẹda, ọmọ ẹda le sọ pe bayii, ki Baba sọ rara, ọna ti oun fẹ fun ọ ree.
Nitori iṣẹ ti Ọlọrun ba ti pari, ko si ẹda alaye to le yẹ ẹ wo. Idunnu lo si jẹ pe igba akọkọ ree, ti ọmọ Yewa-Awori, yoo gbimọ pọ lati fa oludije kan kalẹ lati dupo gomina nipinlẹ Ogun, bi a ba ni ka woo lati ẹyin wa, ṣe ni wọn ma n lo awọn eeyan wọn lati fi tako ara wọn ni.
Bi a ba ni ka sọ nipa iriri, ọkan pataki gboogi ni oludije gomina ADC yii, nitori pe Ọlọrun fun ni ọpọlọ ati iriri nipa bi a ṣe n ṣakoso nnkan to fi n gun rege, eyi ribẹ, nitori aimọye ileeṣẹ lo to n dari ẹ, to si fi n ran awọn eeyan lọwọ.
Tẹlẹtẹlẹ ni apejẹ ADC n jẹ ‘’Dide lati tan’’, ṣugbọn Ọtẹgbẹyẹ ti wa yii pada si ‘’Dide lati jawe olubori’’ nitori ipinnu ẹ ni pe ibo to n bọ yii ẹgbẹ oṣelu naa ni yoo jawe olubori ti oun yoo si di gomina lọdun 2023.
Loootọ Yewa- Awori ni Biyi Ọtẹgbẹyẹ, amọ Ẹgba ti ṣetan lati ṣiṣẹ pọ ki wọn fi ibo wọn gbe e wọle bẹẹ naa ni awọn eeyan Ijẹbu to jẹ ilu ti Mama to bi oludije yii ti wa naa ti ni awọn faramọ ki Yewa Awori di gomina lọdun to n bọ ati pe ko si ẹlomii-in tawọn fẹ ju BOT lọ.
Ologini ti wa ti ajo de o, ki ekute ile paramọ nipinlẹ Ogun, ariwo tawọn araalu si n pa ni BOT, ibo.
No comments:
Post a Comment