Oludije gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APP, nipinlẹ Ogun, Olufẹmi Falana, ti ke gbajare sita pe oun ko mọ nipa ẹjọ kan ti wọn pe oludije gomina fẹgbẹ oṣelu ADC, Agbẹjọro Olubyi Ọtẹgbẹyẹ, bẹẹ loun si ti ṣetan lati tọwọ ofin bọ ọ.
Ninu atẹjade kan ti alaga ẹgbẹ naa Biọla Martins ati akọwe ẹ, Adebisi Samuel, jọ kọwọ bọ fi sita lọjọ Aje, Mọnde, ana, ni wọn ti pe ẹjọ ọhun ti wọn pe ni ile-ẹjọ ijọba apapọ, to wa niluu Abẹokuta, nibi ti wọn ti bẹbẹ pe ki wọn yọ oludije gomina ADC, lati ma ṣe kopa, ninu ibo to n bọ lọdun 2023, gẹgẹ bi eyi ti ko lẹsẹ nilẹ, ti oludije wọn ko mọ nnkankan nipa ẹ.
Wọn sọ pe ẹgbẹ oṣelu ọhun ti ṣetan lati gbe igbesẹ ofin lati fi tako ẹni to ṣonigbọwọ ẹjọ naa, eyi wọn ṣapejuwe gẹgẹ bi ojo. Wọn ẹgbẹ APP, ti wa ni imurasilẹ lati koju Ọtẹgbẹyẹ, ki i ṣe lati bẹbẹ pe ko ma kopa.
Atẹjade ọhun tun wa ṣalaye pe awọn wa fun ifarajin alaafia nipinlẹ yii pẹlu awọn ẹgbẹ oṣelu yooku. Bi ẹ gba gbagbe ni nnkan bi ọsẹ meji sẹyin naa ni wọn gbe iru atẹjade bayii sita, nibi ti wọn sọ pe awọn yẹra patapata si iroyin kan ti wọn gbe jade lori ẹrọ ayelujara pe ki ile ẹjọ da Gomina Dapọ Abiọdun lọwọ kọ, ko ma ṣe kopa ninu ibo gomina to n bọ, ti wọn si sọ pe awọn yoo gbe igbesẹ ofin le e lori, iru ẹ naa ni wọn tun sẹ pe awọn ko mọ nipa ti Ọtẹgbẹyẹ naa.
No comments:
Post a Comment