A fi oju ona tuntun ta a se si Arepo dupe lowo awon araalu- Dapo Abiodun - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday 14 November 2022

A fi oju ona tuntun ta a se si Arepo dupe lowo awon araalu- Dapo Abiodun

Gomina ipinle Ogun, Omooba Dapo Abiodun ti so pe awon fi oju ona tuntun ti won se si Arepo, ti won pe ni  Arepo-Journalists Estate Road, ti won sese si dupe lowo awon olugbe agbegbe naa fun bi won se satileyin fun won ninu ibo to koja ni nnkan bi odun meta seyin. 

Gomina soro yii nibi ayeye ohun to waye lojo Aje, Monde, ose yii bee lo tun mu dawon eeyan loju pe ijoba oun yoo tubo maa mu igbe aye irorun bawon araalu. 

O so pe,"Bi e ba gbagbe lodun 2019, nigba ta a n se ipolongo idobo, mo seleri pe ti mo ba le wole gege bii gomina, mo maa tun ona Arepo to ti baje yii di titunse oun ni mo waa mu se bayii"

Gomima Abiodun to sapejuwe ona naa ni ti igbalode lo so pelu idaniloju pe ko nii tete baje, nitori awon nnkan ti won fi se e. 

O waa sakiyesi pe oju ona yii yoo je ki irinajo, wahala dinku, ti yoo si tun fopin si bi awon moto se n baje lawon agbegbe naa, bee lo tun seleri pe ijoba oun yoo tubo tesiwaju lati maa satunse awon ona to ti baje kaakiri ipinle naa, ti yoo si je ki oro aje tun gbooro si. 

Bee lo tun fikun un pe ijoba tun ti bere atunse ona lori awon ona to so ipinle Ogun ati Eko papo pelu ileri pe yoo pari laipe yii. 

Gomina wa ro awon araalu paapaa julo awon odo lati maa samojuto ona naa, ki won ma se gba oloselu onijagidijagan laaye lati ba a je lakooko ibo to n bo lodun 2023.

Ko to to akoko yii ni Olu tilu Arepo Oba  Solomon Atanda Oyebi, ti dupe lowo gomina lori bo se mu ileri e se lori ona naa.

Ninu oro ti Iyaafin Funke Fadugba, eni to ti figba kan je alaga awon oniroyin nipinle Eko, lo ti so pe ona naa ti baje tele debi pe o pin si meji, o wa gboriyin fun Gomina Abiodun, lori bo se gba won sile, to si bawon tun ona naa se. 

No comments:

Post a Comment

Pages