Ikinni Ọjọọbi;Ọtẹgbẹyẹ gboriyin fun Derin Adebiyi fun ifarajin ijọba demokireesi - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 16 November 2022

Ikinni Ọjọọbi;Ọtẹgbẹyẹ gboriyin fun Derin Adebiyi fun ifarajin ijọba demokireesi


 

Agbẹjọro Olubiyi Ọtẹgbẹyẹ, oludije gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu ADC, nipinlẹ Ogun, ti ba agba ẹgbẹ oṣelu nni, Oloye Derin Adebiyi yọ fun ti ayẹyẹ ọjọọbi ẹ, to n ṣe pẹlu adura pe Ọlọrun yoo ṣafikun erongba ẹ  lati le jẹ ki ijaba dẹmokireesi tubọ gbilẹ nipinlẹ Ogun.

 

Ninu atẹjade ti  ikọ awọn oniroyin fun oludije yii fi sita, ni wọn ti ṣapejuwe Oloye Adebiyi gẹgẹ bi opo nla kan ninu oṣelu, ti ko jẹ kawọn oloṣelu kan yẹpẹrẹ ẹ.

 

" Atẹjade ọhun tun lọ bayii, '' Mo ki agba ọjẹ midii oṣelu, aṣaaju ti ko ṣe fọwọ rọ sẹyin fun ti ayẹyẹ ọjọọbi ti ẹ n ṣe, mo dupẹ lọwọ Ọlọrun fun igbe aye yin, bẹẹ ni mo tun gbadura pe ki Ọlọrun tubọ maa bukun yin pẹlu alaafia, ilera to peye ati ẹmi gungun ninu irin ajo yin''

 

Ọtẹgbẹyẹ tun fikun ọrọ ẹ pe '' Gẹgẹ bi a ṣe mọ, igbe aye dara nigba teeyan ba gbe ohun rere ṣe, O ti lo gbogbo awọn nnkan to ni nipa ẹmi ati ti ara lati fi gbe awọn eeyan agbegbe yin dide paapaa julọ ninu oṣelu. Aṣaaju lẹ maa n jẹ ninu ijijagbara, ẹ ti farajin daadaa fun oṣelu bẹẹ lẹ ti ja lati rii pe idajọ ododo waye nipasẹ oṣelu nipinlẹ yii'

 

O waa sọ pe awọn eeyan ipinlẹ Ogun si n fẹifọwọsowọpọ ẹ lati le jẹ ki iṣejọba rere waye, kawọn eeyan si jẹ mudunmudun ijọba dẹmokireesi.

 

 


No comments:

Post a Comment

Pages