Bashọrun Muyiwa Ọladipọ, ẹni to ti figba kan jẹ kọmiṣanna fọrọ aṣa ati irianjo afẹ, nipinlẹ Ogun, ti gba awọn Yewa-Awori, nimran lati ma ṣe sọ akoko ti wọn tun ni lakooko yii nu lori ipo gomina ninu ibo to bọ lọdun 2023, ki wọn si ri pe wọn ṣatilẹyin fun ọmọ wọn, Biyi Ọtẹgbẹyẹ,labẹ ẹgbẹ oṣelu ADC, to n dije fun ipo ọhun.
Ọkunrin naa sọ pe bi wọn ba tun le sọ anfaani yii ni ko daju pe wọn yoo ripo naa mu lọdun 2027, tawọn kan tan wọn pe ki wọn duro de, ko ma waa dabi ẹni pe wọn ko nii gbọ nipa ẹ mọ.
O ṣalaye pe latigba ti wọn ti da ipinlẹ Ogun silẹ, awọn Yewa- Awori, laarin ẹya ti wọn pin Ogun si ni wọn ko tii gboorun ipo naa, eyi tawọn yooku wọn ti debẹ
Muyiwa Ọladipọ to tun ti figba kan jẹ olori nile igbimọ aṣofin nipinlẹ Ogun, to wa lati Rẹmọ, tun sọ pe, ‘’Lati ọdun 1976 ti wọn ti da ipinlẹ Ogun silẹ, ọmọ Yewa kan ko tii di gomina, ṣe ni wọn n fi ori wọn gba ara wọn kaakiri, lati le jẹ ki wọn padanu, eyi ti ko jẹ ki gbogbo wọn le fi ẹnu ko, lori oludije kan ṣoṣo. Lọdun 1992,nigba ti oludije meji jade laaarin gbungbun Ogun, ẹ maa ranti pe ko sẹni to jade lati Ogun East,nitori Bisi Ọnabanjọ, ti jẹ ẹ tẹlẹ. Titi Ajanaku ati Ṣẹgun Ọṣọba ni wọn jọ jade du ipo gomina, ko to di pe Ajanaku juwọ silẹ fun Ọṣọba. Awọn bii mẹfa ni wọn jade ni Yewa, lati du yii, gbogbo wọn ni ko gba funra wọn lati juwọ silẹ fun ẹnikan’’.
O tun tẹsiwaju pe “Lọdun 1999, awọn meji lo tun jade lati Ogun Central, Ọṣọba ati Fẹmi Okunrounmu. Nigba ti Ọṣọba ko gbogbo ibo ni Ogun East ati Ogun Central, ṣe ni awọn oludije lati Yewa pin ibo mọ ara wọn lọwọ. Bẹẹ naa lo ri lọdun 2011, GNI ati Olurin ni wọn jọ jade ni Yewa. GNI ati Sẹnetọ Ọdunsi ni wọn jọ jade. GNI ati Triple A ni wọn jọ forigbari lati Yewa.’’
O waa sọ pe iyalẹnu lo jẹ pe fun igba akọkọ ninu itan ilẹ Yewa, oludije kan ṣoṣo lo jade dupo naa iyẹn Agbẹjọro Biyi Ọtẹgbẹyẹ.Eyi to sọ pe o tumọ si pe oludije naa ati ti APC, ni wọn yoo kọ waako bayii.
Ọladipọ waa sọ pe ko si nnkan to buru nibẹ ki ọmọ Yewa di gomina lọdun 2023, ko si le wa si imuṣẹ, ki wọn le tun iwe itan kọ, ki wọn ma feti si awọn to n tun fẹẹ sun ogo wọn di 2027, nitori ko sẹni to le sọ nnkan to ṣẹlẹ.
O ni “A le ni oludije to ju mẹta, mẹrin lọ lati Yewa lọdun 2027, ṣugbọn asiko naa ree lati tete beere fun ẹtọ wọn. To ba di 2027, ti oludije kan ba jade lati aarin gbungbun ipinlẹ Ogun, o ti di dandan wi pe awa ti a wa lati Ogun East ko nii gbe apoti ibo, eyi yoo si fun awọn aarin gbungbun lanfaani lati jawe olubori. Awọn Yewa yoo si tun pin ibo laaarin awọn oludije wọn, ki ni a wa n sọ, ẹ jẹ ka sọ otitọ to wa nilẹ.”
No comments:
Post a Comment