Ẹ fọkanbalẹ ko si ewu rara, ile ẹjọ kotẹmilọrun ni a o ti pade- Agbẹjọro ADC - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 25 November 2022

Ẹ fọkanbalẹ ko si ewu rara, ile ẹjọ kotẹmilọrun ni a o ti pade- Agbẹjọro ADC


Ifẹnla Oligbinde, to jẹ oludamọran pataki ni ẹka ofin fun ẹgbẹ oṣelu ADC, nipinlẹ Ogun, ti ni kawọn araalu fọkanbalẹ lori igbẹjọ to waye lonii, nitori  awọn si n lọ sile ẹjọ kotẹmilọrun lati bawọn ṣagbeyẹwo ẹjọ naa daadaa, to si da oun loju pe wọn yoo jawe olubori.

 

Ninu atẹjade kan ti ọkunrin naa fi sita lẹyin ti igbẹjọ waye tan lo ti sọ pe awọn eeyan ti pe akiyesi wọn lori idajọ pe ki ajọ eleto idibo lorileede yii iyẹn INEC, yọ orukọ gbogbo awọn oludije ẹgbẹ oṣelu ADC tipinlẹ Ogun, to fi mọ gomina wọn kuro ninu awọn oludije fun ibo to n bọ lọna yii.

 

O ni, ‘’ Ni bayii nnkan ta a n duro le lori ni ekunrẹrẹ alaye nipa Idi ti ejo na fi ri bẹẹ, awa amofin, to n ṣiṣẹ fun egbe oṣelu ADC,  si ti n ṣiṣẹ lori bi  a o ṣe pe ẹjọ kotẹmilọrun lori ẹjọ ọhun.

 O ni ohun to daju ni pe gbogbo awọn oludije to wa labẹ aṣia ẹgbẹ ADC, lo ṣe nnkan to yẹ ki wọn ṣe gẹgẹ bi ajọ eleto idibo ṣe la a silẹ, eyi ti wọn fi kun oju oṣuwọn bi liana ofin ṣe la silẹ.

 Agbẹjọro ọhun sọ pe gbogbo awọn nnkan wọnyii lo mu dawọn loju pe gbogbo awọn oludije yii pata ni wọn yoo gba ẹtọ wọn pada nile ẹjọ kotẹmilọrun.

 O ni gbogbo ọgbọn ti wọn n da yii ko le da ẹgbẹ oṣelu ADC duro lati gba awọn eeyan silẹ lọwọ ijọba amunisin nipinlẹ Ogun.

 

 


1 comment:

  1. Haa ewo ona awon ota ADC tun gba......
    Olohun jowo ma fun ota ADC lagbara Lori wa o

    ReplyDelete

Pages