APC n ṣe lasan ni ADC lo maa bori wọn- Ọnarebu Eyiowuawi - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 25 November 2022

APC n ṣe lasan ni ADC lo maa bori wọn- Ọnarebu Eyiowuawi

Onarebu Eyiowuawi Rasaq, ọkan lara agba fẹgbẹ oṣelu ADC, nipinlẹ Ogun, ti ni kawọn araalu fọkanbalẹ lori abajade idajọ to waye nile-ẹjọ giga, niluu Abẹokuta nibi ti wọn ti paṣẹ pe ko ajọ eleto idibo, iyẹn INEC, yọ orukọ oludije gomina atawọn ọmọ ile igbimọ aṣofin kuro lara awọn ti yoo dije ninu ibo to n bọ lọdun 2027.

 Ninu atẹjade kan to fi sita, ni ọkunrin to tun jade dupo gẹgẹ bi aṣoju-ṣofin fun ẹkun Abẹokuta North, Ọdeda, Ọbafẹmi Owode, ninu ibo to n bọ naa sọ pe idajọ to waye ọhun ko mi awọn lọkan rara ati pe awọn to ni ẹka idajọ ninu ẹgbẹ ọhun ti ṣetan lati pe ẹjọ kotẹmilọrun.

O sọ pe bigba ti igbẹjọ ṣẹṣẹ bẹrẹ loun ka  ọrọ naa si ati pe iru igbẹjọ bẹẹ ti waye nipinlẹ Adamawa tako ẹgbẹ oṣelu APC, to si ti di itan bayii, tile-ẹjọ tun bakan naa tun yi ẹjọ naa da pada.

Eyiowuawi waa sọ pe. ‘’ Mo fi akoko rọ gbogbo awọn oloolufẹ ẹgbẹ oṣelu ADC, nipinlẹ Ogun, paapaa lawọn ijọba ibilẹ Ogun, lati ma ṣe mi kan rara, ki wọn si jẹ ka pa ọkan pọ pẹlu ireti pe ao ja ajaṣẹgun, a o si le ijọba APC, kuro ni Oke-Mọsan, lọdun 2023.

 


No comments:

Post a Comment

Pages