E jẹ ka jọ fọwọsowọpọ lati di gomina lọdun 2023- Ọtẹgbẹyẹ rọ Yewa-Awori Oke-Okun. - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 23 November 2022

E jẹ ka jọ fọwọsowọpọ lati di gomina lọdun 2023- Ọtẹgbẹyẹ rọ Yewa-Awori Oke-Okun.


 

Oludije gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress (ADC), nipinlẹ Ogun, Amofin Olubiyi Otẹgbẹyẹ,  tun ti sọ pẹlu idaniloju pe oun nikan ṣi ni oludije ti yoo jawe olubori ninu ibo to n bọ pẹlu atilẹyin Ọlọrun.

 

O ni gbogbo eleyii le di mimuṣẹ pẹlu atilẹyin awọn eeyan ipinlẹ Ogun paapaa julọ awọn ọmọ bibi ilẹ Yewa- Awori, awọn lo le ran oun lọwo lati fẹyin Gomina Dapọ Abiọdun to wa nibẹ lakooko yii janlẹ nibi ibo ọdun 2023 ọhun.

 

Ọtẹgbẹyẹ sọrọ ọhun nibi iṣẹ  ti iyawo ẹ, Arabinrin Roli Ọtẹgbẹyẹ, jẹ nibi ayẹyẹ ọdun kẹwaa ati aṣalẹ apejẹ tawọn olujolwo ọmọ ilu Ilaro, ti wọn wa ni United Kindom ati Ireland iyẹn Ilaro Descendant Union United Kingdom & Ireland, ṣagbatẹru ẹ.

 

O sọ pe idunnu lo jẹ foun pe latigba ti ajọ eleto idibo INEC, ti gbe orukọ oun jade gẹgẹ bi oludije fun ipo ọhun loun ti n ri aanu ati atilẹyin gba kaakiri ipinlẹ Ogun. O wa rọ awọn eeyan ẹ ti wọn wa ni Oke-Okun lati jẹ ki wọn jọ wa ni iṣọkan, ki wọn si jọ ṣiṣẹ pọ lati le jẹ ala ẹ yii di mimuṣẹ.

 

 

Ninu atẹjade ti ikọ iroyin Amofin Biyi Ọtẹgbẹyẹ fi sita ninu eyi ti iyawo oludije gomina ọhun ka nibẹ, ti akọle ẹ n je ‘’Ipe fun gbogbo ọmọ ilẹ Yewa-Awori ni Oke-Okun’’, eyi to ṣapejuwe Ọtẹgbẹyẹ gẹgẹ bi alaanu eeyan ni Ilaro ati Yewa-Awori lapapọ

.

O sọ pe, ‘’ Latigba ti ajọ eleto idibo INEC, ti gbe orukọ mi jade ni ọjọ kẹrin, oṣu kẹsan-an, ọdun yii, ni oriṣiriṣi ti n ṣẹlẹ nilẹ  Yewa-Awori, to fihan pe loootọ lawọn eeyan wa ti ṣetan lati rii pe ọkan ninu wa di gomina. Gbogbo awọn nnkan wọnyii ni mo ti papọ, to si jẹ ki igbagbọ mi duro digbi lati jade dupo labẹ ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress (ADC).

 

‘’ Ẹ ma jẹ ki n pirọrọ fun yin gbogbo nnkan lo ti n lọ letoleto koda awọn ti wọn n ro pe a o ti ṣetan ka duro de 2027,ibẹru lo si jẹ ki wọn maa sọ bẹẹ, amọ mo n da wọn lohun lawọn ibeeere ti wọn ko le dahun pe, kin ni idi ẹ ti ko fi jẹ 2023?, Ṣe awọn eeyan wa tun le foritii lati maa jiya fọdun mẹrin mii-in?, Ta lẹni to mọ ẹni ti yoo wa laye lọdun 2027? Njẹ awọn eeyan wa lati aarin gbungbun Ogun, yoo tun fọwọlẹran, ti wọn yoo tun faye ọhun silẹ ni 2027? Ṣe ko tun ni jẹ ibi ti ọpọ oludije yoo tun ti jade lati Ogun West lati wa dije ni 2027, Kin ni o le mu wa tiraka lọfun 2027, ti a ko ba le gba tikẹẹti ọhun ni 2023.

 

Oludije gomina ọhun tun sọ pe bi iṣejọba APC, ṣe n ṣe ilẹ Yewa-Awori, ninu ijọba ko jẹ nnkan to tẹ gbogbo araalu lọrun ati pe ipo ti wọn n fi wa si ko bojumu rara ninu ijọba wọn. O ni bi a ba ni ka bẹrẹ nipa eto ẹkọ, ipo ti wọn wa ko ṣe e fẹnu sọ bakan naa nipa ilera, itiju lo si n jẹ ti wọn ba de ọpọ ile iwosan, to jẹ pe awọn eeyan ko ri itọju to peye.

 

“ Pẹlu bawọn iya wa atawọn iyawo wa ṣe n ṣiṣẹ to, ṣe ni wọn n ko wọn si oko ẹru gbese, bẹẹ lawọn ọmọ wa lọkunrin ati lobinrin ni wọn fojoojumọ koju iṣoro airiṣẹ, ti ọjọ iwaju wọn gan-an ko ye wọn mọ pẹlu bi wọn ṣe kawe gboye lawọn ileewe giga. Awọn ajinigbe ti gbakoso gbogbo awọn abule wa, to jẹ ibẹrubojo lawọn eeyan ọhun fi n gbe, bẹẹ lawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun ati afiniṣoogunowe naa ti gbode’’

 

Bẹẹ ni Ọtẹgbẹyẹ tun sọ pe ‘’ Awọn oju ọna wa ti bajẹ debi pe awọn araalu ko le gbe mọto wọn kọja, mo mu da yin loju pe bi mo ba le di gomina nipinlẹ Ogun, mi o ni dẹru wiwo le awọn araalu lori, nitori mo mọ iṣẹ wa ni lati gbe awọn eeyan dide, ki wọn kuro ninu iṣẹ, kawọn naa si le jẹ anfaani mudunmudun ijọba tiwa-n-tiwa’’

 

Oludije gomina ọhun wa rọ awọn Yewa-Awori, ti wọn wa ni Oke-Okun, lati ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ọba alaye ati oun gẹgẹ bi oludije ti ko ni atako, ki wọn jọ wa niṣọkan, ki wọn jọ parapọ rii pe gbogbo ọmọ ilẹ Ilaro ati ọmọ bibi Yewa Awori, ati ipinlẹ Ogun, ni wọn forukọsilẹ ti wọn si ni kaadi idibo ti wọn yoo fi dibo foun gẹgẹ bi gomina ipinlẹ Ogunb, lọjọ kọkanla, oṣu kẹta, 2023.

 

O ni oun mọ awọn ipa pataki tawọn ọmọ bibi Yewa-Awori n ko fun idagbasoke ilu ati pe bawo loun ṣe le gbagbe awọn igbesẹ ti wọn gbe lakooko aisan korona ni nnkan bi ọdun meji sẹyin.

 

 

No comments:

Post a Comment

Pages