Ọ̀tẹ́gbẹyẹ ṣèlérí láti ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọba alayé nípínlẹ̀ Ògùn - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 29 October 2022

Ọ̀tẹ́gbẹyẹ ṣèlérí láti ṣiṣẹ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọba alayé nípínlẹ̀ Ògùn


Agbẹjọro Biyi Ọtẹgbẹyẹ,oludije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress (ADC), ti ṣeleri lati ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn ọba alaye nipa fifun wọn nipo to yẹ ninu ijọba, to ba di gomina lọdun 2023.

 

Ninu atẹjade ti ikọ iroyin ọkunrin naa fi sita, eyi to fọwọ si lati fi ki Olowu tiluu Owu, Ọba Saka Matẹmilọla ku oriire ọba tuntun to jẹ ati ayajọ ọdun Owu, to waye lonii. Ni o tun ti sọ pe awọn ọba alaye gbọdọ wa ni ipo ọwọ ninu iṣejọba oṣelu lati le jẹ ki alaafia ati isọkan jọba kaakiri ipinlẹ Ogun.

 

Oludije Gomina tun ṣalaye pe oun nireti pe oun gbọdọ maa ya ninu ọgbọn ati iriri awọn ọba naa lati maa fi ṣakoso ijọba lọna to yoo mu idagbasoke ba ipinlẹ Ogun lapapọ. O waa ki Ọba Matẹmilọla, ku oriire ori itẹ awọn babanla ẹ to gun yii, pẹlu apejuwe ipo naa lati fi sin awọn araalu ati lati fi ṣagbega awọn aṣa. O sọ pe oun kpo siyemeji pe ilẹ Owu yoo tubọ maa dagba si ninu isọkan ati idagbasoke rere ti ọba naa yoo mu bawọn lakooko tiẹ.

 

Ọtẹgbẹyẹ ni ‘’ Kabiyesi, bi awọn afọbajẹ ṣe mu yin tijọba ipinlẹ si yan yin ti wọn gbe ade le yin lori, jẹ yiyan lati ọrun wa, Mo waa dupẹ lọwọ Ọlọrun fun aanu ati ọla ẹ lori yin. Ẹ o pẹ lori oye awọn babanla yin’. 

 

Oludije naa waa pari ọrọ ẹ nipa gbigba awọn araalu Owu lamọran lati fọwọ so wọpọ pẹlu Ọba tuntun naa, o ṣeleri pe oun yoo tubọ ṣiṣẹ lati le jẹ ki ajọṣepọ to danmọran wa laarin gbogbo ọba nipinlẹ naa.

 

 

No comments:

Post a Comment

Pages