Eto n lọ lọwọ lori bi a o ṣe maa yan ọba ni Orile- Ilawọ laisi wahala- Ọba Macgregor - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 29 October 2022

Eto n lọ lọwọ lori bi a o ṣe maa yan ọba ni Orile- Ilawọ laisi wahala- Ọba Macgregor


 

Orile Ilawọ ti wọn ṣẹṣẹ yan, Ọba Alexander Oluṣẹgun Macgregor, ti itan imọlẹ sọrọ kan lọsẹ to kọja pe ijọba ipinlẹ Ogun lo yan oun gẹgẹ bi ọba ki i ṣe pe boya wọn da ifa kankan.

 

Ọba alaye ọhun sọrọ yii lakooko to n ba awọn oniroyin sọrọ, o sọ pe ko si nnkan ti ifa nii ṣe pẹlu bi wọn ṣe yan oun, o ni ko si ibi kankan ti wọn n pe ni idile to n jọba ni Orile-Ilawọ, nitori pe ijọba lo da bi wọn ṣe n jọba lagbegbe naa silẹ.

McGregor tun ṣalaye pe '' Loootọ awa marun-un la jade dupo, ṣugbọn emi ni mo jawe olubori ninu ibo tijọba ṣagbatẹru ẹ. Ọdun1999, ni wọn ijọba da Orile-Ilawọ silẹ nigba naa baba mi ni Oluwo Ilawọ ati Lisa Ẹgba, ko tiẹ si nnkan to n jẹ ọba rara.''

O fikun ọrọ ẹ pe Balogun ni ẹni to kọkọ jẹ olori Ilawọ, baba baba oun si ni laarin ọdun 1916 si 1966. O ni baba to bi oun lo ṣẹṣẹ gbe igbesẹ bi ilu naa yoo ṣe maa de ade gẹgẹ bi ọba nilẹ Ẹgba.

Macgregor tun sọ pe ''  Awọn ajeji, ti wọn ki i ṣọmọ Orile-Ilawọ, nijọba ibilẹ Ọdẹda, nipinlẹ Ogun, ni wọn n fẹhonu han kiri nipa iyansipo mi.Ijọba ipinlẹ Ogun lọwọ si iyansipo mi. Awọn afọbajẹ wa nibẹ pẹlu, ibo mẹfa lo gbe mi wọle ninu mẹsan-an''

Ọba tuntun tun ṣalaye siwaju pe oju oori baba oun wa ninu ọgba ile naa, ki wọn fi le mọ pe awọn ṣe alejo nilu ọhun. O ni inu awọn araalu si dun pe wọn fi oun jọba.

O sọ pe ‘’Awọn ti wọn n fẹhonu han kiri, ti wọn ni mi o ki i ṣe ọmọ Ilawọ ki i ṣe araalu Ilawọ o, atọhunrinwa ni gbogbo wọn, ajeji ni wọn. Ọmọ ale eeyan ni i patan ilu ẹ rederede, ti i fọwọ osi juwe ile baba rẹ, ọmọ ọkọ Ilawọ lemi’’

Ọba  yii sọ pe koun tiẹ to depo ọba loun ti ran awọn eeyan lọwọ, nitori pe nnkan ti oun ba ninu ẹbi toun ti jade ni, o ni ki wọn maa ṣe anu jẹ awọn logun pupọ, idi niyii lo fi ni awọn araalu fi tubọ fẹran oun.

Ọjọgbọn to kawe gboye, to si ni imọ ati iriri nipa eto ipoogun iyẹn Pharamacy ni Ọba tuntun naa, bo ṣe nileeṣẹ nla lorileede yii bẹẹ naa lo ni ni oke-okun, bakan naa la gbọ pe ọpọ awọn eeyan ni wọn jẹ labẹ ọba alade yii.

 


No comments:

Post a Comment

Pages