Ko digba teeyan ba to sọ ko to mọ pe loootọ lawọn araalu Orile-Ilawọ wa lẹyin ọba tuntun ti wọn ṣẹṣẹ yan iyẹn Ọba Alexander Oluṣẹgun Macgregor, nitori bi wọn ṣe tu yaya jade lati jẹ ko gbogbo agbaye mọ pe inu awọn dun si ọba tuntun naa.
Lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii lawọn eeyan ọhun to fi mọ awọn ọlọdẹ nijọba ibilẹ Ọdẹda, jade si igboro Abẹokuta, ti wọn si n rin kaakiri pẹlu awọn kaadi lọwọ wọn ti wọn kọ oriṣiriṣi akọle si, eyi ti wọn fi dupẹ lọwọ Ọlọrun pe o fawọn ni ọba tawọn nifẹẹ si.
A gbọ pe nnkan to jẹ kawọn eeyan yii wọ inu idunnu nla lọ ni pe wọn dupẹ pe awọn bọ lọwọ awọn onijẹkujẹ ti wọn sọ ile aye di tara wọn, to jẹ pe aye familete ki n tutọ ni wn jẹ kaakiri latigba ti Ọba Adedapọ Aina, ti waja.
Wọn ni ayọ nla lo waa jẹ fawọn pe Macregor to gboye ọjọgbọn ninu iṣẹ oogun pipo, ni wọn dibo yan gẹgẹ bi ọba, eyi ni gbogbo wọn ṣe fi ẹmi imoore wọn han ti wọn si sọ pe yoo mu idagbasoke nla ba awọn ati agbegbe wọn.
Ọkọọkan lawọn eeyan naa sọrọ ti wọn si mu da Ọba tuntun naa loju pe awọn wa pẹlu ẹ. Lara wọn ni olori ọdọ Ilawọ ati Alagbagba, Fatai Balogun ati Muyideen Ọmọtọshọ.
Awọn eeyan naa ṣalaye bo ṣe jẹ pe Macgregor n ran awọn ọdọ lọwọ pẹlu ipese iṣẹ, bo ṣe jẹ ọpọlọpọ ọmọ lo ti fun lẹkọọ ọfẹ nileewe, ironilagbara lọtun-losi ni wọn tun sọ pe o jẹ kinu awọn dun pe oun ni yoo tukọ Ilawọ bayii, awọn ko si ni i pada lẹyin rẹ nigba kankan.
Irin kaakiri awọn eeyan naa tun gbe wọn de ọdọ Ọṣilẹ Oke-Ọna Ẹgba, Ọba Adedapọ Tẹjuoṣo, bẹẹ ni wọn tun de Aafin Olowu tuntun, Ọba Saka Matemilọla, wọn de Aafin Agura, Ọba Saburi Iṣọla Bakare,ọdọ Alake ilẹ Ẹgba, Ọba Adedọtun Arẹmu Gbadebọ, ni wọn pari irin wọn si lọjọ naa.
Bakan naa ni Olori Ọdẹ Ilawọ, Oloye Idowu Tajudeen, kin awọn olori ọdọ naa lẹyin pẹlu alaye pe lati nnkan bii ọdun marun-un sẹyin ni ọba ti wọn ṣẹṣẹ yan yii ti n ṣe awọn nnkan manigbagbe fawọn eeyan agbegbe rẹ.
O ni Oluṣẹgun Macgregor lo ṣe ina ‘Solar’ fawọn, o tun gbẹ kanga igbalode ti wọn n pe ni ‘borehole’, ironilagbara to si tọwọ rẹ wa ko ṣee gbagbe.
Ninu ọrọ Ọba Oluṣẹgun Macgregor, o kọkọ dupẹ lọwọ awọn eeyan ọhun fun atilẹyin wọn. Pẹlu ileri pe oun ko nii jẹ ki wọn kabamọ pe oun jẹ ọba lori wọn., O waa ṣeleri fun wọn pe gbogbo agbara loun yoo sa lati rii pe awọn nnkan to tọ si wọn labule lawọn yoo maa ṣe fun wọn.
No comments:
Post a Comment