Ko seni to dibo aare fun Tinubu ti yoo kabamo- Ajihinrere Remilekun Adeniji - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday 31 October 2022

Ko seni to dibo aare fun Tinubu ti yoo kabamo- Ajihinrere Remilekun Adeniji


 
Ajihinrere Remilekun Adeniji, to je alakoso agba fegbe awon onigbagbo to n satileyin fun Asiwaju Bola Ahmed Tinubu, fun ibo aare to n bo lona, ti muu dawon eeyan loju pe ko seni to dibo fun oludije naa to kabamo.

Obinrin naa soro yii lakooko to se ipade po pelu awon oloye ati adari egbe naa ti won wa lorileede yii.  Eyi to waye niluu Eko laipe yii.

Bee lo tun ro awon eeyan lorileede yii lapapo lati ma se ri Tinubu to je elesin musulumi ati igbakeji e, toun naa je elesin kan naa gege bi eni ti yoo sise lati tako awon onigbagbo ti won ba de ijoba kaka bee ki won ka won bii elesin won ti yoo mu ilosiwaju ati idagbasoke ba wa.

 
O fikun oro e pe awon oludije ohun labe egbe oselu APC ti ko ipa won fun ilosiwaju awon onigbagbo.


Remilekun tun so pe, " Mo fee ran yin leti pe Iyawo Tinubu iyen Seneto Oluremi Tinubu,atawon omo e igbagbo ni won, koda o tun ko ile ijosin sile ijoba tawon gomina ti won de leyin e si n lọ titi di akoko yii.

 Bee lo tun mu da Asiwaju Bola Tinubu loju pe awon yoo rii pe o ri ibo milionu marun-un latodo egbe onigbagbo to n satileyin fun un, ninu ibo to n bo naa.

 

No comments:

Post a Comment

Pages