Ẹgbẹ oṣelu Action Peoples Party, iyẹn APP, ati oludije gomina wọn, nipinlẹ Ogun,Olufẹmi Falana, ti sọ pe awọn ko mọ nnkankan nipa iroyin kan ti wọn lẹnikan gbe jade lori ẹrọ ayelujara, nibi to ti n bẹbẹ nile-ẹjọ pe ki wọn yọ orukọ Gomina Dapọ Abiọdun, kuro gẹgẹ bi oludije gomina fẹgbẹ oṣelu APC, nibi ibo to n bọ lọdun 2023.
Ninu atẹjade ti alaga ẹgbẹ naa nipinlẹ Ogun, Biọla Martins ati akọwe ẹ, Adebisi Samuel, fi sita lonii, ni wọn tun ti ṣeleri pe awọn yoo fọwọ ofin gbe ẹnikẹni ninu ẹgbẹ ọhun to ba ṣonigbọwọ iru iroyin bẹẹ.
Gẹgẹ bi wọn ṣe wi, wọn ni awọn ka ẹni to sọ bẹẹ gẹgẹ bi ọlẹ, ti ko ni ọkan akin, ti ko si tun ni ero rere pẹlu Gomina to to ṣe bẹbẹ fawọn eeyan ipinlẹ Ogun. Wọn ni ẹgbẹ awọn ti ṣetan lati koju ẹ nibi ibo gomna to n bọ naa, nitori oludije wọn ti wa ni igbaradi.
Atẹjade ọhun tun ka bayii, ‘ A fi atẹjade ti a gbe jade yii fi yọ ara wa kuro ninu iroyin ti ko lẹsẹ nilẹ, eyi to kun fun titako Gomina ipinlẹ Ogun. A gba pe Dapọ Abiọdun, ti ṣe daadaa fawọn eeyan ninu eyi ti ẹgbẹ oṣelu wa fẹẹ ba figbagbaga ninu ibo to n bọ lọdun 2023’’.
No comments:
Post a Comment