Ìyà ńlá ni ìjọba Dàpọ̀ Abíọ́dún fi ń jẹ àwọn òṣìṣẹ́-fẹ̀yìntì nípínlẹ̀ Ògùn- Ọ̀tẹ̀gbẹ́ye - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 29 October 2022

Ìyà ńlá ni ìjọba Dàpọ̀ Abíọ́dún fi ń jẹ àwọn òṣìṣẹ́-fẹ̀yìntì nípínlẹ̀ Ògùn- Ọ̀tẹ̀gbẹ́ye


Lati bi ọsẹ meloo kan sẹyin ni nnkan ko ti rọgbọ laarin Gomina Dapọ Abiọdun tipinlẹ Ogun ati ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ-fẹyinti, lori ẹtọ wọn, ti wọn si n gba ọrọ ọhun bi ẹni gba igba ọti.

 

Ṣugbọn ni bayii, Agbẹjọro Biyi Ọtẹgbẹyẹ, to n dupo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu

African Democratic Congress (ADC) nipinlẹ Ogun, ti barajẹ pupọ lori bo ṣe ni ijọba to wa lode yii n faye awọn eeyan ọhun ta kati.

 

Ninu atẹjade kan, Oloye Wọle Elegbede, to jẹ oluranlọwọ pataki fun iroyin fi sita lorukọ oludije naa lo ti ṣalaye pe ẹdun ọkan lo jẹ foun lori ọrọ awọn oṣiṣẹ fẹyinti ọhun, nitori ọpọ wọn lo ti ku lori bi ijọba to wa lode yii ṣe n fẹtọ awọn eeyan naa dun wọn.

 

O sọ pe bawọn eeyan ba ri bi Gomina Abiọdun, ṣe n ṣagbekalẹ owo ifẹyinti awọn oṣiṣẹ nibi ipade gbọngan fun ti eto iṣuna 2023, to waye niluu Ijẹbu-Ode yoo ro pe ootọ lo n gbe jade nipa laimọ pe asọdun lo pọ.

 

O ni nibẹ ni Gomina ti kede pe owo to kọja biliọnu aadọrin naira nijọba oun ti san fawọn oṣiṣẹ fẹyinti lati ọdun 2019. O ni bigba to mọ ọn mọ tan awọn araalu jẹ ni.

 

Ọtẹgbẹyẹ tun ṣalaye pe okodoro ọrọ farahan ninu ọrọ ti  Ọgbẹni Waidi Oloyede, alaga fẹgbẹ awọn oṣiṣẹ fẹyinti nipinlẹ Ogun, ati Ṣẹgun Ọbadimu, toun jẹ alukoro wọn, sọ jade pe biliọnu mẹta pere ni ijọba Dapọ Abiọdun, ti san fawọn lati ọdun 2019, to ti gori aleefa.

 

O ni awọn eeyan ọhun tun sọ pe ọpọ awọn eeyan wọn ni wọn gbowo ifẹyinti wọn to yẹ ki wọn gba ninu oṣu kẹsan-an, ni ọjọ kejidinlogun, oṣu kẹwaa, nigba ti wọn ko si mọ igba ti oṣu kẹwaa yoo yọju.

 

 

Oludije gomina tun fikun ninu ọrọ ẹ pe irọrun araalu lo yẹ ko jẹ ijọba to ba wa lode lọkunkundun, ki i ṣe imọtara ẹni nikan. O ni ijọba to ba kuna lati ṣe nnkan tawọn eeyan n fẹ, to jẹ pe afi tiẹ lo n ṣe, o ni iru wọn ko yẹ lawujọ, o si yẹ ki wọn gba iru ijọba bẹẹ danu lori ilẹ.

 

O ni ko si yẹ ki wọn gba iru ijọba bẹẹ lati kọja ọdun 2023, ti ADC, yoo fi gbajọba.

 


No comments:

Post a Comment

Pages