Ijoba ibile Odeda kede Olusegun Macgregor gege bi oba tuntun ni Orile Ilawo - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 21 October 2022

Ijoba ibile Odeda kede Olusegun Macgregor gege bi oba tuntun ni Orile Ilawo


Ijoba ibile Odeda nipinle Ogun, ti kede Oloye Olusegun Macgregor gege bi oba tuntun ni Orile Ilawo,leyin ti won ti dibo fun aye oba to sofo naa.

Gege bi leta kan ti Ogbeni Makinde Zacheus Adio, to je akowe nijoba ibile naa fi sita loruko alaga won, ti won si n gbero lati fi sowo si Osile Oke-Ona Egba, Oba Dokita Adedapo Tejuoso, lati mo nipa e ko to di pe won yoo fi sowo si ijoba ipinle Ogun.

Leta ohun ti won fi sowo si wa ti akole e je "Wi wa aye si ipo oba to sofo ni Orile Ilawo"", ni won ti salaye pe gege bi ase tawon gba lati ileese to n ri si ijoba ibile ati oye jije ati ofiisi Gomina ti nomba e jeC HM II/4/145 of lojo kejilelogun osu kejo, odun 2022 ati CHM II/4/154 ti ojo kokandilogbon, osu kesan-an, odun yii bakan naa lati gbe igbese ona abayo si ipo oba to sofo yii.

 Bee ni won tun so pe nipa ase ohun ni ijoba ipinle se fowo si awon afobaje mesan-an lati seto oba naa laarin ojo merinla

Ipade yii ni won so pe o waye lojo ketala osu yii ni Kegunmela, nile Oloye Olufade Anthony Ajani lati yan oba tuntun fun Orile Ilawo yii.

Nibe ni won so pe gbogbo omo bibi ilu Orile Ilawo ti yan Oloye Olusegun Alexander Macgregor, Ogbeni Kashimawo Aremuu Bakare, to je akowe agbegbeOke Abelu Ilawo lo dabaa nigba ti Arabinrin Khadijat Badejo, sikeji ti gbogbo awon yooku naa fowo si.

‘Won bo tile je pe eni ti won jo dupo ko yoju niOsi Ilawo  ni ki won dibo. Nibe ni Olusegun Alexander Macgregor  ti jawe olubori pelu ibo mefa, ti won si fun ni iwe eri.No comments:

Post a Comment

Pages