Ẹgbẹ awọn onimọ iṣiro owo iyẹn Institute of Chartered Accountant of Nigeria, ICAN, ti ki Sẹnetọ Solomon Adeọla, to jẹ alaga igbimọ to n ri si eto isuna, nile igbimọ aṣofin, niluu Abuja, ku oriire ami ẹyẹ CON ti Aarẹ Mohammadu Buhari, fi da a lọla laipẹ yii.
Ninu atẹjade kan ti Oloye Kayọde Ọdunaro, to jẹ alakoso fun eto iroyin fun ọkunrin yii fi sita lonii, lo ti ṣalaye pe wọn ki aṣofin naa ku oriire ninu lẹta ti aarẹ ẹgbẹ naa Mallam Tijjani Musa Isa, ati igbakeji ẹ, Dokita. Innocent Okwuosa, fi le e lọwọ lorukọ ẹgbẹ naa lakooko ti wọn lọọ ki ni ọfiisi ẹ niluu Abuja.
Ẹgbẹ naa ṣapejuwe ami ẹyẹ naa gẹgẹ bi ipa ti ọkunrin naa ti ko fun idagbasoke orileede yii, ti wọn lo si tun safihan awọn iṣẹ rere to ti ni bi akọsilẹ fun un.
Aarẹ ẹgbẹ ICAN ọhun tun ṣalaye siwaju pe’’ Awa nigbagbọ pe ẹ o tun tẹsiwaju lati maa ṣe ojuṣe yin gẹgẹ bi apẹẹrẹ aṣaju rere, eyi tawọn ọmọ orileede yii fi le mu yin yangan kaairi titi di onii’’
Nigba to n fesi, Sẹnẹtọ Adeola, toun naa jẹ ọmọ ẹgbẹ ICAN, dupẹ pupọ lọwọ wọn ati pe inu oun maa n dun lori ọgbọn ati oye ti wọn lati jẹ ki erongba ẹgbẹ onmọ iṣiro owo ko ku, kaka bẹẹ o tun fi gbooro si. O ni oun amuyangan lo jẹ foun pe oun gba idanilẹkọọ labẹ ẹgbẹ naa.
O ni “Mo maa tẹsiwaju ninu erongba mi lati rii pe ICAN, ṣi wa nipo aṣaaju ti wọn wa lorileede yii’
No comments:
Post a Comment