Mi o lo kowo bowe adehun pelu Adebutu o- Segun Sowumi - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday 18 October 2022

Mi o lo kowo bowe adehun pelu Adebutu o- Segun SowumiOtunba Segun Sowumi, oludije fun ipo gomina labe egbe oselu PDP nipinle Ogun, ti so pe ipade toun lo se pelu akegbe oun, Onarebu Ladi Adebutu ki i se lati kowo bowe adehun bi ko se ki alaafia le joba ati lati wa ojutu si wahala to n fojoojumo waye.

Okunrin naa soro yii lakooko to n ba oniroyin wa forojomitoro oro lori foonu laaaro yii.

Otunba Sowumi so pe ipade oun pelu Adebutu to waye lana-an niluu Iperu ni lati jo soro papp nitori agba ki i wa loja, ki ori omo tuntun wo, nitori pe gbogbo awon ti won ni awuyewuye ninu egbe naa loun yoo sabewo si lati ba won soro.

O fikun oro e pe "Ko seni to je ojulowo omo oko ti yoo gbadura pe ki Ile baba oun baje. Bi nnkan se n lọ ninu egbe PDP, ko seni to dun mo, idi niyi to mo fi gbe igbese lati wa ona ti iyanju yoo fi wa Lori awon awuyewuye naa.

Sowumi tun salaye pe ki i se pe lati lo bebe tabi se adehun gege bi aheso tawon kan so, bi ko se bi alaafia yoo sejoba ti gbogbo wa yoo jo fimo sokan.

No comments:

Post a Comment

Pages