Jimi Lawal ni kawon eeyan e fokanbale, ile-ejo lo maa yanju e - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday 17 October 2022

Jimi Lawal ni kawon eeyan e fokanbale, ile-ejo lo maa yanju e


Oludije gomina to sese jawe olubori ninu ibo abele PDP, Ogun to waye, Jimi Lawal, ti so fawon omoleyin e lati fokanbale, nitori ko si ewu ati pe ile-ejo lawon yoo tun pada si.

Okunrin naa soro yii ninu atejade kan ti agbenuso e nipa iroyin, Austin Oniyokor, 
fi sita lori bi egbe oselu PDP Ogun se so pe ki Jimi Lawal atawon merin kan lo rokun nile fun Igba die naa.

Losan yii ni egbe naa kede pe ki Jimi Lawal atawon merin mi-in toruko won je  Bola Odunmosun,to je akapo egbe naa,  Fasiu Ajadi, Kola Akinyemi atiTope Asiru, loo sinmi fun Igba die nile nitori bi won se se ibo abele mi-in 

Otunba Jimi so pe igbese ti won gbe ohun ko ja mo nnkankan bi ko se lati fi tun da wahala sile ninu egbe naa.

O ni oro won waa dabi ohun lohun Jakobu, amo owo ni owo Esau. O ni nnkan to ba ni lokanje pupo ni pe ninu ijoba tiwa-n-tiwa lorileede yii awon kan si le maa ko ara won jo labe orule enikan ti kootu ti pase pe ki atundi ibo waye, ki won si so pe awon da awon kan ti won pase Ile ejo mo duro.

O ni nnkan to si han gbangba ni pe won fee yi ofin Ile ejo pada ki won so pe awon ti da eni to bowo fun ofin duro ninu egbe, nitori idi eyi atundi ibo naa naa ko ma ba less nile. Sugbon o ni Olorun ju won lo

Pelu gbogbo eleyii, o ni gbogbo igbese won ko le duro niwaju ofin, ati pe gbogbo iwa odi ti won hu lawon yoo gbe lo sile ejo

Won ni ko to to Igba naa awon ro gbogbo awon agba egbe, awon alatileyon ati araalu pe ki won se suuru,nitori gbogbo awon nnkan bayii ninu oselu lo n bo wa rekoja.

No comments:

Post a Comment

Pages