Jimi Lawal gbegba oroke nibi ibo abele atundi PDP Ogun - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday 17 October 2022

Jimi Lawal gbegba oroke nibi ibo abele atundi PDP Ogun Ni nnkan bi ose meloo kan nile ejo pa lase pe ki ibo atundi waye ninu egbe oselu PDP ipinle Ogun, nitori ona ti won gba di tele, ko bofinmu.

Ni bayii, ibo ohun ti waye gege bi ase ile-ejo, Otunba Jimi Lawal, lo si gbegba oroke gege bi oludije gomina labe PDP, nipinle Ogun.

Ibo abele ohun lo waye ni gbongan DLK Events Center, niluu Abeokuta nigba ti won tun tawon omo Ile igbimo asofin, asoju-sofin ati asofin agba di lawon agbegbe won.

Ibo irinwo le ni marun-un din logota ni Jimi Lawal ni to ti gbeye mo awon yooku e lowo.

Onarebu Bola Odumosu, to je akowe isuna egbe ohun, to saaju awon oloye yooku wa sibe, lo kede esi ibo ohun.

O so pe awon asoju irinwo le ni metalelogota lo kopa nibi ibo to waye yii

O ni ibo meje ni won gbegile nigba tawon oludije gomina yooku, iyen 
 Onarebu Ladi Adebutu, Otunba Segun Sowunmi ati  Abodunrin John Abimbola ko ni ibo kankan.

A o ranti pe eemeji otooto nile ejo giga to wa niluu Abeokuta ti pase pe ki ibo atundi waye, to si je pe se ni alaga egbe naa Sikirulae Ogundele so pe ko si nnkan to je ibo abele nitori awon oloye egbe lapapo ti n gbe igbese.

No comments:

Post a Comment

Pages