Dapo Abiodun ko ni eto rere fawon araalu-Otegbeye - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Monday 17 October 2022

Dapo Abiodun ko ni eto rere fawon araalu-Otegbeye


Oludije gomina fegbe oselu ADC, nipinle Ogun, ninu ibo to bo lodun 2023, Agbejoro Biyi Otegbeye, ti so pe ijoba Dapo Abiodun ti kuna lati mu igbe aye irorun bawon to n sejoba le e lori ati pe ko ni eto rere kan fawon araalu. 

Pelu idaniloju pe gbogbo nnkan ni yoo pada bo sipo ti egbe oselu ADC, ba gbajoba ninu ibo to n bo naa 

Oludije naa soro yii ninu atejade kan tawon iko iroyin e fi sita, eyi to te wa lowo.

Lojo Abameta, Satide, ose to koja yii, ni Gomina Abiodun se ipade po pelu egbe NATA, amo kaka ko bawon nipa bi nnkan se n lọ si nipinle Ogun sugbon won ni ete lo n fi sile to n pa lapalapa.

Atejade ohun tun lo bayii" Kaka ki Gomina gba le ijoba oun ti mu ijakule bawon eeyan, ko si so ooto pelu eje to to da lati mu igbe aye irorun bawon eeyan ipinle Ogun, se lo kan fi akoko sofo pelu awon eeyan to soko eebu"

Won ni lakoko naa, o ki Abiodun mo pe awon eeyan ipinle Ogun ki i se omode ti won gbe korun lọ si oko,nipa awon ere omode to fe maa se.

Pelupelu e se ni won so pe o kan mu atamo mo atamo, to si fi nnkan to je awon eeyan niya sile,won eyi to fi n se iyen, o ye ko wa ona lati pari ija pelu ore e atijo, to tun je oloore e.

Otegbeye tun so pe gbogbo wa la mo, ta a si gba pe ki i se gbogbo eeyan la fun ni ogbon lati dari, awon mii-in kan ba ara won nibe.

Sugbon awon kan ti won ko agbara tabi fun ni ogbon ati dari,ti won ba ba ara won nibe, maa n si asilo ti eri okan ko si je ki won gbadun.

Oludije gomina ADC naa tun salaye pe ipinle Ogun n gbe ni akoko to je pe gbogbo nnkan ini wa ni won yoo ta tan, ti won yoo si ko owo e sinu apo osuwon won.

O ni edun okan lọ n je pe ipinle Ogun wa ni igbekun lodo awon ti won ko le sanwo osu osise deedee kaka bee oro aje enu won ni won ja si nibi ti won yoo ti maa ele.

O wa fikun isoro awon ilu to wa ni aala to ye ki won mojuto, won ko ri si, se ni won da awon naa ni bi omi isanwo.

Bee lo ni awon owo to ye ki won ma si ona lati fi se atunse won ni won dari e si ona mii-in

Amo bayii, Otegbeye ti wa mu dawon eeyan ipinle naa loju pe ki won se suuru, nitori olugbala won ti yoo yo won kuro ninu ofin fee de. Ati pe laarin osu marun-un akoko ni ayipada rere yoo ti maa de bawon, nigba ti egbe oselu ADC,ba gbakoso ti Agbejoro Biyi Otegbeye, ba di gomina ipinle Ogun.


No comments:

Post a Comment

Pages