Bo tile je pe o ku die ki ipolongo ibo gomina bere, Gomina tele nipinle Ogun, Asofin Ibikunle Amosun, ti so nigbangba pe oun ko le satileyin fun Gomina Dapo Abiodun, to fee dije fun ipo naa leekeji kaka bee Agbejoro Biyi Otegbeye to jade dupo labe egbe oselu ADC ni oun too satileyin fun.
Asofin yii soro naa lakooko to n kopa nibi iforowero ti ileese BBC Yoruba se fun in. O ni gbogbo ona loun yoo fi satileyin fun Otegbeye lati rii pe o jawe olubori ninu ibo to n bo naa.
Okunrin naa to wa ninu egbe oselu APC, salaye pe oun gbe igbese naa nitori iwa ti Dapo Abiodun hi sawon omoleyin oun.
Amosun so pe oun ko le gba kawon omo egbe e ti won ti kopa Ida ogorin lati je ki egbe wa titi di oni, wa deni ti won yoo maa ye.
O tun so pe fun ibo ipo aare oun mu da gbogbo eeyan ipinle Ogun loju, koda ki won ni igun meta ni won, enikan soso naa lawon yoo di fun.
Amosun salaye siwaju pe"Mo nigbagbo pe gbogbo wa la a ni oludije kan , bo tile je pe mi o mo inu awon eeyan yooku e,amo mo nigbagbo pe oludije kan soso la ni fun ipo aare ti a maa dibo fun"
"Amo fun ipo gomina o, idije ona otooto ni, mi o le sise fun APC,se e mo mo so fun yin pe ko si lose kan ki n ma wale,ti mi o ba wa, inu mi ki i dun, nitori awon eeyan mi naa si ni. Awon eeyan yii si ti sise fun egbe APC, ti won ko si se won daadaa".
O ni ko si nnkan ti won fee so nipa APC ipinle Ogun, tawon ko ko ipa aadorin si ogorin, pelu atileyin Olorun, o ni enikan ko le wa de ko waa da gbogbo awon to ti sise fun egbe nu.
O ni loooto awon ki i se Olorun, sugbon oun ko le wa leyin alabosi, nnkan tawon kan so nipa oun ni pe aimoye nnkan ni oun ko le jade so sita. Amo bayii oun ti wa jade so sita fun gbogbo eeyan.
No comments:
Post a Comment