Shuaib Afolabi Salisu, oludije fun ipo ọmọ ile igbimọ aṣofin, fun ẹkun aarin gbungbun ipinlẹ Ogun, labẹ All Progressives Congress, APC, ninu ibo to n bọ, ti pe ipe fun gbogbo eeyan lati jẹ ki orileede yii tubọ ni idagbasoke ati ilọsiwaju.
Ọkunrin yii pe ipe ọhun fun ti ikinni ku oriire ayẹyẹ ọdun kejilelọgọta ti orileede wa gba ominira, eyi ti wọn ṣe ayajọ ẹ lonii. O sọ pe ohun to ṣe pataki ni maa ṣajọyọ ọdun naa, nitori ohun lo mu wa bọ loko ẹru awọn oyinbo amunisin.
Salisu tun fikun ọrọ ẹ pe o yẹ ki a maa fi ifẹ orileede wa ṣe akọkọ lọkan wa si gbogbo nnkan ta a ba n ṣe. O ni bo tilẹ jẹ titi di akoko yii ni a ṣi fi n tiraka, lati le duro ba awọn orileede yooku lagbaaye ṣugbọn idaniloju wa pe a yoo debẹ lọjọ kan.
Oludije fun ipo sẹnetọ labẹ APC, tun ṣalaye siwaju pe ka sọ ti ododo loootọ ni Ọlọrun bukun wa lorileede yii, ti a ṣi n ri aanu gba, amọ o ṣe ni laanu pe awọn aṣaaju wa kan n ṣilo nitori iwa imọtara ẹni to n ba wọn ja.
Eyi lo si sọ pe o n fa ijakulẹ ta a foju winna. O wa sọ pe ka lo akoko ayajọ ọdun kejilelọgọta ta a n ṣe yii lati fi ronu awọn nnkankan to le mu wa tẹsiwaju lorileede yii, ki a si fi wa ni imurasilẹ
O tun sọ pe ‘’ Bi ibo gbogbogboo ọdun 2023, ṣe n sunmọ wa yii, ta a si n koju ipenija lati sọ awọn ohun kọ yala ere tabi adannu awọn nnkan to ti ṣẹlẹ sẹyin. Ẹ jẹ ka farabalẹ lati yan aṣoju ta a mọ pe yoo wa iyanju si iṣoro to de ba wa. Mo si tun fẹẹ ki ẹ mọ pe ẹgbẹ oṣelu APC, ko wa lati ja yin ni tan-mọ ninu gbogbo nnkan ti a n ṣe’
No comments:
Post a Comment