Ayẹyẹ ọdun ominira; Ọtẹgbẹyẹ ni ireti si wa fawọn ọmọ ipinlẹ Ogun - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 1 October 2022

Ayẹyẹ ọdun ominira; Ọtẹgbẹyẹ ni ireti si wa fawọn ọmọ ipinlẹ Ogun


 

Agbẹjọro Biyi Ọtẹgbẹyẹ, oludije gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress (ADC), ti fọkan awọn eeyan ipinlẹ Ogun balẹ pe didun ni ọsan yoo so ti wọn ba fi le dibo foun ninu ibo gomina lọdun to n bọ.

 

O sọ pe ireti wa pe gbogbo iṣoro tawọn ọmọ ipinlẹ naa doju kọ ni yoo di afi sẹyin bi oun ba le gba isakoso lọwọ awọn ti wọn ṣi agbara lo tijọba wa lọwọ wọn lakooko yii.

 

Ninu iṣẹ to ran si gbogbo awọn ọmọ ipinlẹ Ogun, fun ti ayẹyẹ ọdun kejilelọgọta, ti orileede yii gba ominira lọwọ awọn oyinbo amunisin. O kọkọ ki awọn araalu pe wọn ku oriire ajọdun naa.

 

Ọkunrin to da ajọ kan ti wọn pe ni ‘’Anfaani ipilẹ fọjọ iwaju’’ iyẹn Building Opportunities For Tomorrow (BOT), tun ṣalaye ṣiwaju pe ireti rere toun mẹnuba yii ko pẹ mọ, o ti wa lẹgbẹ awọn eeyan ipinlẹ Ogun.

 

Oludije naa sọ pe Mo fẹẹ mi da yin loju pe ẹgbẹ oṣelu ADC yoo ṣatunto lori ijọba tiwa-n-tiwa ti yoo jẹ anfaani fun gbogbo mutumuwa,awọn nnkan ta a mọ si ohun imayedẹrun ti araalu yoo fi mọ pe awọn nipa ninu ijọba ni ẹgbẹ wa yoo ṣe, ti yoo se de ile, de oko’’

 

O tun fikun ọrọ ẹ pe laipẹ yii ẹgbẹ oṣelu ADC yoo gbe erongba ẹ eyi ti yoo fi ọkan araalu balẹ, ti yoo ṣatunṣe rere lori ọrọ aje, eto aabo to peye, ayika to dara fun okoowo, ṣiṣe agbega lori alaafia ilu paapaa laarin awọn ẹlẹsin,pari pari ẹ ni gbigbe ipinlẹ Ogun soke ju awọn ẹlẹgbẹ ẹ lorileede yii.

 

Ọtẹgbẹyẹ tun rọ gbogbo awọn ọmọ orileede yii lapapọ pe ki wọn ni suuru,orileede yii le mati de ibi ti wọn ro lọkan pe o yẹ ko de ṣugbọn ireti wa fọjọ iwaju pe gbogbo ẹ a ri bi a ṣe n fẹ. Bẹẹ lo ni akoko ta a wa yii, ki a ma ṣe fi adura silẹ.

 

O waa gbadura pe laipẹ laijinna orileede yii yoo di eyi to kun fun wara ati oyin.

 

No comments:

Post a Comment

Pages