Ayeye odo Iyake ni Ado-Awaye yoo waye ninu osu kokanla odun yii-Oba Folakemi - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 2 October 2022

Ayeye odo Iyake ni Ado-Awaye yoo waye ninu osu kokanla odun yii-Oba Folakemi


Alado tiluu Ado-Awaye, Oba Ademọla Olugbile Folakanmi ti kede pe gbogbo eto lọ ti n lọ lowo fun ti ayeye odo Iyake todun yii, eyi ti yoo waye lojo kerindinlogun si ojo kokandinlogun, osu kokanla odun yii.

Gege bo se wi, o ni ayeye naa lawon yoo ti gba awon alejo kaakiri ile Afrika ati awon oyinbo ti won lati ba won se.

Oba naa tun fikun ninu atejade kan ti won fowo si pe ori oke Ado Awaye ni ayeye ohun yoo ti waye

O salaye pe ayeye ohun je atewogba latodo ipinle Oyo bi okan lara irinajo afe iyen Tourism.

Bee lọ tun seleri pe ojo merin otooto ti won fa kale lawon ti pese eto fun igbadun ayeye ohun. Lara e ni isin ajosepo, idije ere idaraya, asale awon oba alade,idije ijo atawon nnkan mii in.

Kabiyesi tun fi kun oro e pe oun sagbekale ayeye odun Iyake lagbaaye fun igbega ilu naa, eyi to so pe yoo tun mu irepo wa fun gbogbo omo ilu naa.

O tun mu dawon eeyan loju pe gbogbo awon ayeye ohun yoo tun so won papo, nitori awon to wa leyin odi naa ni won n bo wa sile lati bawon sajoyo.

Lara awon ti won reti lojo naa ni Gomina Seyi Makinde, tipinle Oyo, ti yoo je alejo pataki. Igbakeji e, Agbejoro Bayo Lawal, bee ni won tun reti awon gomina lati Ile Yoruba gbogbo.

Okere tilu Saki, Oba Oyeniyi Olabisi Oyedele, to tun je igbakeji igbimo Oba nipinle Oyo ni Baba ori ade lojo naa.


No comments:

Post a Comment

Pages