Wọ́n ní Amósùn kò mọ̀ nípa ìwe àdéhùn tí Ládi Adebutu àti Akínlàdé ṣe láti fi pín ipo - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 24 September 2022

Wọ́n ní Amósùn kò mọ̀ nípa ìwe àdéhùn tí Ládi Adebutu àti Akínlàdé ṣe láti fi pín ipo


Lọsẹ to kọja ni aṣiiri iwe adehun kan to waye laaarin oludije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, Ọnarebu Ladi Adebutu ati ẹni to fẹẹ fi ṣe igbakeji ẹ, iyẹn Abdulkabir Akinlade, lori bi wọn ṣe fẹẹ pin ipo bi wọn ba wọle ibo lọdun 2023.

Bo tilẹ jẹ pe latigba ti iroyin iwe adehun ọhun ti tu sita lawọn eeyan ti n sọ ẹhonu wọn lori igbesẹ tawọn mejeeji ọhun fẹẹ gbe, amọ nnkan tawọn to jẹ ọmọ lẹyin Sẹnetọ Ibikunle Amosun n sọ ni pe ọga wọn ko mọ nnkankan nipa  iwe naa.

Ati pe Akinlade ko jẹ ki ọga ẹ yii mọ ko to gbe igbesẹ ọhun. Ọkunrin yii lo darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu PDP, lẹyin ti wọn ko ti fun un ni tikẹẹti lati dije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APC.

Nibi iwe adehun ọhun ti wọn pe akọle ẹ ni adehun aṣepapọ, nibẹ ni wọn sọ pe Sikirulae Ogundele, alaga PDP, nipinlẹ Ogun ati akọwe ẹgbẹ naa, Sunday Solarin, ti wọn ṣoju ẹgbẹ wọn nibi adehun ọhun nigba ti Tọla Banjọ naa wa nibẹ, ti wọn si ṣeleri fun Akinlade lati fun awọn eeyan ẹ nisẹ ti wọn ba wọle gomina.

Bẹẹ lo wa ninu ẹ pe ẹgbẹ oṣelu PDP, gbọdọ fi ipo igbakeji gomina, aṣofin lati ẹkun Ogun West ati ọmọ ile igbimọ aṣofin meji  ni ẹkun aarin gbungbun Ogun fun Akinlade atawọn eeyan ẹ.

Bakan naa la tun gbọ pe wọn tun adehun pe bi Ladi Adebutu ba di gomina, Akinlade atawọn eeyan ẹ ni APC/APM, yoo gba ipo kọmiṣanna meje, oludamọran Pataki mẹẹẹdogun, oluranlọwọ pataki, ogun,marun-un fun igbimọ bọọdu ati alaga ijọba ibilẹ marun-un pẹlu.

Adehun ọhun tun tẹsiwaju bayii’’ Ẹgbẹ mejeeji wọle adehun asepọ lati lo gbogbo ọrọ oṣelu papọ lati fi jawe olubori ninu ibo to n bọ lọdun 2023, labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP.

‘’ fun itẹsiwaju eleyii, Ọnarebu Akinlade gbọdọ wa ọnọ lati sa awọn eeyan jọ loriṣiriṣi ọna fun aṣeyọri PDP lati wọle fun ipo gomina ipinlẹ Ogun, bẹẹ lo gbọdọ ṣatilẹyin, ṣeranwọ, ko si mu agbega wa fun Ọnarebu Ladi Adebutu’’

Bẹẹ la gbọ pe titi di akoko yii si ni wahala abẹnu bẹ silẹ laaarin awọn ọmọ ẹyin Ladi Adebutu, ti wọn si n sọ pe to ba tiẹ ṣee ṣe tawọn ba wọle ninu ibo ọhun, ipo wo lo fẹẹ ku fun awọn, nigba ti wọn ti sọ bi wọn ṣe fẹẹ ṣe laarin wọn.

Ṣugbọn awọn ti Amosun sọ pe bigba ti eeyan dalẹ ọga ẹ lawọn ka iwa ti Akinlade naa hu si, to si jẹ pe nitori tiẹ naa ni ọga wọn fi gba idalẹbi lọdọ awọn kan titi di omi.

Ati pe wọn ni ki lo da Ladi ati Akinlade loju pe wọn yoo bori ibo ninu ibo to n bọ yii pẹlu awọn ẹjọ to wa ni kootu bayii, wọn ni afaimọ ki wọn ma kan abuku bọ nidi ẹ.

 


No comments:

Post a Comment

Pages