Kò sí wàhálà kankan lórí ọ̀rọ̀ ọba Ìtèlé-Ọba Ademọla Ẹlẹtu - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 24 September 2022

Kò sí wàhálà kankan lórí ọ̀rọ̀ ọba Ìtèlé-Ọba Ademọla Ẹlẹtu


 Ọba Ademọla Ẹlẹtu Aṣorota, Onitẹle tilu Itele, ti rọ awọn araalu lati ma ṣe tẹti si awọn ọrọ to le da wahala silẹ, eyi ti wọn ni ẹnikan ti wọn pe orukọ ẹ ni Adogun Atele, n gbe kaakiri, eyi to sọ pe o kun fun irọ. 

Ninu atẹjade ti Azeez Salakọ, to jẹ akọwe afin ilu Itele fi sita lorukọ ọba naa lo ti rọ awọn araalu lati ma ṣe feti si gbogbo isọkusọ ti wọn lọkunrin naa n ṣọ kaakiri, ti wọn ka si ibanilorukọ jẹ.

Akọwe yii lawọn gbe atẹjade naa sita lati fi tako iroyin kan ti wọn ni Adogun naa kọkọ fi sita, to pe akọle ẹ ni ˆIpo ọba Itele, Aṣorota, oludije APC, Afọlabi Afuapẹ n fẹwọn ṣere’

O ni awọn ka iryin ọhun si bi ẹni pe Adogun Atele yii ti n wa ọna tẹlẹ lati fi ba ijọba ipinlẹ Ogun, ẹgbẹ oṣelu APC, paapaa julọ Afọlabi Afuapẹ, to jẹ oludije fun ipo aṣoju-ṣofin fun ẹkun Abẹokuta South, lorukọ jẹ ni.

Nipa ẹsun ti wọn kan ọkunrin naa pe o ta iipo ọba Onitele  tilu Itele-Ọta fun Ọba, Ademọla Ẹlẹtu-Aṣorota. Ni akọkọ, wọn sọ pe ko si ninu ẹjọ ti wọn pe, ti wọn gbe jade ti wọn ti ni ẹri lati fi gbe ẹsun wọn yii lẹsẹ.

Akọwe ọhun tun fikun ọrọ ẹ pe nitori ọkunrin naa ti lulẹ lori ipo ọba to n du, ti ko si ri ọna mii-in mọ lo mu ko ma sọ isọkusọ kaakiri lati fi wa olugbeja.

Atẹjade ọhun tun ka bayii,  Afin ọba Onitele tilu Itele-Ọta fẹẹ sọ di mi mọ pe ọna ti wọn gba yan Ọba Musiliu Ademọla gẹgẹ bi ọba ki i ṣe pe nitori gbogbo ilu fẹẹ nikan kọ bi ko ṣe a tẹle gbogbo igbesẹ to yẹ ki a gbe gẹgẹ bi ofin ṣe la a silẹ fun wa. Nitori idi eyi, awọn eeyan ilu ko ri ti ọkunrin  naa ro rara fawọn ẹsun ti ko lẹsẹ nilẹ to n gbe kaakiri”

O ni’’ Ṣe ẹyin naa ko ri pe alawada ni ọgbẹni naa, to fi ọfiisi kọmiṣanna fọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ silẹ, to waa ki oṣelu bọ, to darukọ APC, ko sọrọ nibẹ jare’

O wa pari ọrọ ẹ pe latigba ti Ọba Musiliu Ademọla Eletu-Aṣorota, ti gori itẹ awọn babanla ẹ lo ti n mu inu awọn araalu dun fawọn oun idagbasoke ati ọna to n gba ṣejọba ẹ


No comments:

Post a Comment

Pages