Ipinle Ogun gbaradi fun ayajo irinajo afe lagbaaye - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 23 September 2022

Ipinle Ogun gbaradi fun ayajo irinajo afe lagbaaye



Gbogbo eto lo ti to bayii fun ayajo irinajo afe lagbaaye,elekarundinlaaadota iru e, ti yoo waye lojo Isegun, Tusidee, ojo ketadinlogbon osu yii ni gbongan asa ibile ni Kuto, niluu Abeokuta, aago mewaa ni eto ohun too bere.

Ninu atejade ti Arabinrin Abimbola Otegbade, to je akowe iroyin ni eka ileese to ri si asa ati irinajo afe fi sita ti Onarebu Adijat Adeleye-Oladapo, to je komisanna nileese ohun fowo si, lo ti so o di mi mo pe akole ayajo odun yii ni Atunro lori irin ajo afe.

Gomina Dapo Abiodun, tipinle Ogun ni too je olugbalejo pataki lojo naa bakan naa lawon ajo to nii se pelu irinajo afe ko nii gbeyin lojo naa.

Gege bi komisanna tun se wi,awon iwe apileko latodo awon agba ti won ti ni iriri nipa irinajo afe yoo waye, ijo ibile lorisirisi, ere Ori itage latodo awon egbe osere kaakiri ko ni gbeyin lojo naa.

O fikun oro e pe awon ajo to n ri si irinajo afe lagbaaye ta a mo si United Nations World Tourism Organisation (UNWTO),  ni won dii di ya ojo naa soto fun ipolongo irinajo afe lati le mo anfaani to mu ba oro aje wa lapapo.

O ni nnkan ti won fee jiroro le lori yoo tubo je ki isokan ba irinajo afe nitori ko yo enikeni sile fun ojo iwaju.

No comments:

Post a Comment

Pages