Wọ́n ni Salisu ko ri tawon oloselu ẹ̀tanú ro - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Friday 23 September 2022

Wọ́n ni Salisu ko ri tawon oloselu ẹ̀tanú ro


Bo tilẹ jẹ pe ko tii ju wakati mẹrinlelogun ti ajọ eleto idibo iyẹn INEC, gbe orukọ awọn oludije fun ipo aarẹ, igbakeji ẹ, ọmọ ile igbimọ aṣofin niluu Abuja ati Asoju-ṣofin jade sita, lawọn kan ti bẹrẹ si fẹẹ ma fi oṣelu ṣe ẹtanu.

 

Lara awọn ti wọn fẹ maa fẹnu ṣaata ni Alaaji Shuaib Afolabi Salisu, to jẹ oludije fun ipo aṣofin fun ẹkun aarin gbungbun, nipinlẹ Ogun, labẹ ẹgbẹ oṣelu APC.

 

Latigba ti wọn lorukọ ọkunrin naa ti jade ni wọn sọ pe wọn lawọn kan ti dide lati maa ba ọkunrin oludije naa jẹ ṣugbọn tawọn kan sọ pe ọkunrin yii ko ri ti wọn ro, nitori fila mawobẹ, ni wọn sọ pe o de.

 

Shuaib Salisu, to ti figba kan jọ olori awọn oṣiṣẹ Gomina Dapọ Abiọdun, ko to kọwe fipo silẹ lati le raaye kọjumọ ipolongo ipo to fẹẹ dije du lawọn

 

A gbọ pe wọn lawọn kan wa ti wọn ṣonigbọwọ fawọn ti wọn fẹẹ maa fẹnu ṣaata ọkunrin yii ati pe iru ẹ ko le ṣe ko ma waye lakooko ti oṣelu ba ti n lọ, bo ṣe n lọ yii.

 

Ẹnikan to tiẹ ba wa sọrọ sọ pe latigba ti Salisu ti jade dupo lo ti n ṣe awọn ipade kaakiri awọn ijọba ibilẹ mẹfẹẹfa to wa labẹ ẹkun aarin gbungbun ipinlẹ Ogun, ati pe nnkan ti wọn lo n fa ẹtanu yii ko ṣe lẹyin pe gbogbo ibi ti wọn n de, ni wọn ti n ba ọwọ ọkunrin naa pade, to si n ṣẹru ba wọn ni gbogbo igba.

Awọn kan tiẹ sọ pe ọpọ awọn eeyan to wa nijọba ibilẹ Ọdẹda nibi ti wọn gbe bi ọkunrin lo ti janfaani awọn iṣẹ ribiribi, to ti gbe se ninu igbesi aye wọn.

 

Pẹlu gbogbo ẹ, awọn eeyan agbegbe aarin gbungbun ipinlẹ Ogun, ti wa sọ pe ko si ibajẹ tawọn oloṣelu kan le ṣe, to le di kawọn maa ṣatilẹyin fun Salisu ninu ibo to n bọ lọdun 2023 gẹgẹ bi aṣofin agba.

 


No comments:

Post a Comment

Pages