Ọnarebu Adijat ba Ọlọfin Iṣẹri ṣajọyọ ọdun kan lori oye - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 15 September 2022

Ọnarebu Adijat ba Ọlọfin Iṣẹri ṣajọyọ ọdun kan lori oye


 

  Ọnarebu Adijat Adelẹyẹ-Ọladapọ, kọmiṣanna fọrọ aṣa ati irinajo afẹ, nipinlẹ Ogun, ti ṣapejuwe Ọba Sulaiman Adekunle Bamgbade, Ọlọfin tiluu Ishẹri, nilẹ Awori, gẹgẹ bi aṣaaju rere to ti fi apẹẹrẹ rere le lẹ latigba to ti gori itẹ awọn babanla ẹ.

 

Ninu atẹjade ti Kọmiṣanna naa fọwọ si, fun ti ayẹyẹ ọdun kan ti ọba naa gori oye. Ọnarebu sọ pe inu oun dun pe Ọlọrun fi ọba to ni akinkanju, ti ko si mu aye le fawọn eeyan tiẹ, jinki awọn to jọba lee lori, o ni awokọṣe rere ni lawujọ.

 

Ọnarebu to ti figba kan jẹ ọmọ ile igbimọ aṣofin fun ẹkun Ifọ keji lẹẹmeji ọtọọtọ nipinlẹ Ogun fikun ọrọ ẹ pe iru awọn eeyan tawọn araalu n fẹ ni Ọba Adekunle, O waa gbadura pe ki Ọlọrun tubọ fun ni okun ati agbara ti yoo fi maa tukọ ilu Iṣhẹri ilẹ Awori, lọna tootọ, to si yẹ,

 

O tun sọ `pe ‘’ Inu mi dun lati darapọ mọ ọpọ awọn eeyan lati ba Ọba Bamgbade yọ fun ọdun kan lori oye,awọn iṣẹ ẹ yin latigba ti ẹ ti dori oye tun jẹ kawọn araalu nigbagbọ ninu yin’

 

"Aṣaaju rere ti ko ṣe e fọwọ rọ sẹyin ni Adimula ilẹ Awori nitori  bo ṣe tubọ mu igbega ba awọn aṣa ilu naa pẹlu ifọwọsowọpọ pẹlu awọn araalu. Mo waa gbadura pe ki Ọlọrun jẹ ki Ọba Bamgbade pẹ lori oye, ki aṣeyọri nla ko tubọ maa tẹsiwaju niluu naa lakooko tirẹ, Ki Ọlọrun si tun fun yin ni ẹmi gungun ati alaafia, ti ẹ yoo fi ṣejọba pẹ fawọn eeyan Ishẹri, ilẹ Awori’’.

 

 


No comments:

Post a Comment

Pages