Ẹ ẹ ma jẹ ki wọn fowo tan yin jẹ ninu ibo to n bọ- Harrison Adeyẹmi - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Thursday 15 September 2022

Ẹ ẹ ma jẹ ki wọn fowo tan yin jẹ ninu ibo to n bọ- Harrison Adeyẹmi


 

Harrison Adeyẹmi, oludije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu African Alliance Congress nipinlẹ Ogun, ti rọ awọn araalu lati ma ṣe jẹ ki wọn tun fi owo tan wọn jẹ ninu ibo to n bọ lọdun 2023.

 

Ọkunrin naa sọrọ yii lakooko to n kopa nibi eto ori redio kan niluu Abẹokuta, O sọ pe bi wọn ṣe n fowo ra ibo jẹ nnkan to n mu ifasẹyin ba ijọba tiwa-n-tiwa lorileedee yii.

 

O sọ pe kawọn araalu farabalẹ daadaa lati wo iri eeyan ti wọn fẹẹ dibo fun, O waa ṣapejuwe ara ẹ gẹgẹ bi oludije to ku oju oṣuwọn laarin awọn gomina yooku ti wọn fẹẹ jọ dije nipinlẹ Ogun.

 

O ni erongba oun ni lati mu igbe aye irọrun bawọn eeyan rere ipinlẹ Ogun, ki wọn si le jafaani ijọba demọkireesi yii daadaa.

 


 


No comments:

Post a Comment

Pages