Gbadebọ Rhodes-Vivour, oludije ipo gomina labẹ oṣelu Labour, nipinlẹ Eko, ti sọ pe ahesọ ọrọ lasan lawọn kan n gbe nigboro pe APC lawọn ṣiṣẹ fun ninu ẹgbẹ wọn, o ni wọn kan fẹẹ fi ṣi awọn eeyan oun lọkan ni ati pe o da oun loju pe oun loun yoo di gomina ipinlẹ naa lọdun 2023, nitori ibo awọn araalu ni yoo gbe oun wọle.
Ọkunrin yii sọrọ ọhun lakooko ifọrọwamilẹnuwo to ṣe pẹlu oniroyin wa lori ipinnu ẹ lati di gomina lọdun to n bọ. Ẹkunrẹrẹ nnkan to ba waa sọ niyii.
Ki lo mu erongba ati di gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu Labour ipinlẹ Eko waye?
Ẹ ṣe pupọ awọn agba bọ. wọn ni okùn ò níi gùn, kó má níbi tó ti gùn wá, tí kò bá sìi níidí, obìnrin kì í jẹ́ kúmólú, ohun ti mo n sọ ni pé àìsí ètò ìsẹjọba tó múnádókó, ìjọba ti ko ṣẹtán láti gbọ́ ti araalu, ijoba ti ko ṣetan lati gbọn iṣẹ ati iya danu lara awọn eeyan ipinlẹ Eko.
Ijọba ti ko ṣetan lati ṣeto awọn ohun imuayedẹrun fawọn araalu, gbogbo wa o si ni jokoo sibi kan ki a maa woran, ki awon kan waa ba Eko tiwa jẹ.
Yoruba bọ, wọn ni ọmọ ale lo n fi ọwọ osi juwe ile baba rẹ. ojulowo ọmọ Eko ni mi, mo si mọ awọn nnkan ti awọn ara Eko n fẹ. Ẹgbẹ Labour si ree, oun nikan ni ẹgbẹ to ko gbogbo eeyan mọra julọ ninu gbogbo ẹgbẹ oṣelu to wa lorileede yii.
Ko dabi awọn kan to jẹ pe awọn bọrọkinni ara wọn nikan lo wa nibẹ. Lati ṣeto ijọba tiwa-n-tiwa to jẹ ojulowo, ti yoo fi ifẹ awọn eeyan ṣiwaju ohun gbogbo. Awọn nnkan yii lo mu mi dije labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu Labour.
Njẹ ipo to yẹ ki ipinlẹ Eko wa lakooko yii lo wa?
Hmmm, Ẹyin gan-an mọ ninu ọkan rẹ pe ipo ti ipinlẹ Eko wa yii kọ lo yẹ ko wa, nitori pe pẹlu ọpọlọpọ itan to rọ mọ ọn latọjọ pipe wa, o yẹ ko ti tayọ kọja ibi to wa yii. O yẹ ki igbin ẹ ti fa kuro nibi tana an, ki ọpọn rẹ ti sun siwaju
Lori ọrọ Baba isalẹ nidii oṣelu ṣe ẹ nigbagbọ ninu ẹ?
Rara, mi o nigbagbọ ninu baba isalẹ, bo ti wu ki o mọ, nitori pe gẹgẹ bi ọdọ, a gbọdọ le daa duro lati ṣeto ijọba ti ko nii maa jabọ fun baba isalẹ nitori pe ọpọ awọn to n sa kijokijo tẹle wọn lanaa, opolopo wa la mo nnkan to gbẹyin wọn lẹyin ti aarin wọn daru.
Njẹ ẹ ro pe ko nii ṣoro fẹgbẹ Labour lati gba akoso lọwọ APC, ti wọn ti wa nijọba tipẹ?
Rara, ko si ohun to ṣoro ṣe fun Oluwa, koda, nnkan ti ko pẹ mọ ni. Nitori pe gbogbo ara Eko lo ti ri aṣeju ijọba APC, ati ailakoyawọ to si jẹ pe awọn ara Eko gan-an lo n pe fun omi tuntun, mo si mọ daju pe ẹgbẹ mi, Labour yoo fi ẹyin APC le lẹ ninu idibo to n bọ
Ọdọ niyin, ipo agba si gomina jẹ, bawo lẹ ṣe fẹẹ ṣe, ti ẹru naa ko fi nii wuwo?
Haaa, mo ti sọ nigba kan pe ẹni nla lo gbọdọ ṣe nnkan nla, ọdọ to ni okun ati agbara, ti alaafia rẹ si pe perepere lo le ṣe adari Eko, ọdọ ni mi loootọ, ṣugbọn iriri mi nipa iṣejọba kun fọfọ ju awọn to ku lọ, nitori pe mo ni ibaṣe pẹlu awọn eeyan kaakiri nipa oṣelu
Bawo ni ẹgbẹ oṣelu Labour ṣe rinlẹ to nipinlẹ Eko?
Ẹgbẹ wa ko ṣẹṣẹ de, ẹ ẹ ma gbagbe pe ẹgbẹ Labour ti bori lawọn ipinlẹ kan lorileede yii ninu idibo diẹ sẹyin, ẹgbẹ wa fẹsẹ rinlẹ gan-an ni nipinlẹ Eko, to si da mi loju pe a maa jawe olubori
Awọn kan sọ ahesọ kaakiri pe awọn ẹgbẹ oṣelu APC fẹẹ lo yin fun irinṣẹ ni ẹ ṣe wa ninu Labour, ẹ tan imọlẹ si ọrọ naa?
Ahesọ lasan gbaa ni, koda awuyewuye bẹẹ ko tiẹ gba ibi kankan jọ ara wọn. Ko si ki iru aheso bẹẹ ma waye, wọn kan n sọ ki wọn le fi ṣi awọn eniyan mi ati awọn ololufẹ mi lọna ni, ko si ohun to jọ bẹẹ rara.
Ipo wo lẹ fẹẹ fawọn obinrin si ninu ijọba yin?.
Nitori pe awọn obinrin ni iya wa, mo si fila fun awọn obinrin ooo. Mi o ni kọyan wọn kere rara ninu ijọba mi, nitori pe ipa tawọn obinrin yoo ko ninu ijọba mi ki I ṣe kekere . Ẹ jẹ ki a maa fa okun rẹ bọ na…
No comments:
Post a Comment