Ọnarebu Adijat Adelẹyẹ-Ọladapọ, to jẹ kọmiṣanna fọrọ aṣa ati irinajo afẹ nipinlẹ Ogun, ti gba ẹgbẹ awọn olorin nimọran lati lo iṣẹ wọn fi polongo aṣeyọri ijọba ati aṣa lapapọ.
Obinrin naa sọrọ yii lakooko ti ẹgbẹ awọn onifuji tipinlẹ Ogun, ṣabẹwo lọ sọdọ ẹ, o sọ pe ki wọn lo apero ti wọn pinnu lọkan lati ṣe lati fi ṣe awọn atunṣe nipa awujọ bẹẹ ki wọn tun lo lati ṣagbega ijọba to wa lode yii fawọn araalu.
Ko to to akoko yii, ni Ọmọọba Ojoye, to jẹ akọwe iroyin wọn ti ba kọmiṣanna ọhun ṣajọyọ lori ipo tuntun ti wọn ṣẹṣẹ yan an si. O ni awọn ipa ti obinrin naa ti ko sẹyin lawujọ ki i ṣe keremi.
Bẹẹ lo tun lo akoko naa lati fi tọrọ ajọṣepọ to danmọran laarin ẹgbẹ awọn onifuji ati ijọba ipinlẹ Ogun.
No comments:
Post a Comment