Ẹ sọ fun Dapo Abiọdun ko ma da sọrọ ọba Ibu Onipe l’Abigi-Ọnarebu Harrison Adeyẹmi - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 11 September 2022

Ẹ sọ fun Dapo Abiọdun ko ma da sọrọ ọba Ibu Onipe l’Abigi-Ọnarebu Harrison Adeyẹmi


 

Oludije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu Alliance Action Congress (AAC), nipinlẹ Ogun, Ọnarebu Harrison Adeyẹmi, ti gba Gomina Dapọ Abiọdun, ni ikilọ pe ko yẹra lati ma ṣe da tabi yan ọba tipatipa le wọn lori ni ilu Ibu Onipe, nijọba ibilẹ Abigi, Ogun Water side.

O sọ pe oun to ṣe pataki ni fun  un lati tẹle ilana tawọn afọbajẹ ati aṣa ilu ọhun ba la kalẹ lori bi wọn ṣe n jọba lọhun.

O  ṣalaye pe bigba teeyan fẹẹ da wahala silẹ niluu naa ni ọrọ naa, ti apa Gomina gan-an ko ni lee ka to ba bẹrẹ. o ni gbogbo igbesẹ ti Ọmọọba Abiọdun n gbe laipẹ yii lori ọrọ atiyan ọba sori itẹ nibẹ lo ti foju han pe o fẹẹ fi da rogbodiyan silẹ niluu ọhun..

Ọnarebu  to ti figba kan jẹ aṣoju wọn fun ẹkun Ogun Waterside, nile igbimọ aṣofin, ipinlẹ naa tun fikun ọrọ ẹ pe  lati nnkan bi ọdun mẹta sẹyin ti wọn ko ti nọ ọba niluu ọhun.

Ṣugbọn ẹdun ọkan lo waa jẹ fawọn pe Gomina fẹẹ lo awọn oloye kan lati yan ọba tuntun tawọn eeyan ilu ko fẹ, ti wọn si sọ pe awọn ko gba. O ni kaka ki yoo fi maa da si awọn ọrọ ti ko kan yii, ko kuku kọju mọ iṣẹ ilu atawọn ileri to ṣe fawọn eeyan.

 


No comments:

Post a Comment

Pages