Lọsan onii, ni ikọ kan lara awọn oludije gomina fẹgbẹ oṣelu PDP, nipinlẹ Ogun, Ọtunba Ṣẹgun Ṣowunmi tun ju bọmbu kan silẹ fawọn ti wọn jọ n dije fun ipo naa ninu ibo to n bọ lọdun 2023, nigba to sọ pe ko sẹni to ni owo tabi ọrọ lati ra ipo toun dije fun naa mọ oun lọwọ.
Ọkunrin yii sọrọ ọhun nigba to n bawọn oniroyin kan sọrọ, o sọ pe elo ni onitọhun fẹẹ ni to le sọ pe oun fẹẹ ra ipo ọhun mọ oun lọwọ, ati pe oun tiẹ woo ko sẹni to niru ẹ. Bẹẹ lo tun sọ pe ahesọ ọrọ ni eyi tawọn kan n gbe kaakiri pe awọn oloṣelu kan n lo oun lati dabaru ẹgbẹ oṣelu PDP ipinlẹ Ogun.
O ni nnkan toun ja fun loun si n ja fun pe ibo to gbe Adebutu wọle ko le duro lẹgbẹ eyi to gbe oun wọle, nitori gbogbo ilana ati ofin ti wọn ni kawọn tẹle loun tẹle. O sọ pe ọrọkọrọ ti ko ṣe gbọ seti lọrọ ọhun.
O waa beeere pe elo ni oloṣelu ọhun ni to fẹẹ ra oun lati maa da wahala silẹ, o ni erongba oun ni lati jẹ ki ọrọ aje ipnlẹ Ogun, ko burẹkẹ si, kawọn eeyan si maa gbe igbe aye irọrun.
Ṣowumi tun ṣalaye siwaju pe ‘’ o maa n ri bakan loju ti mo gba gbọ ahesọ ọrọ yii, ki lo de ti ironu awọn eeyan kọn fi lọọ bẹẹ, ko sẹni to lowo tabi ọrọ ọhun lọwọ lati ra mi. Awọn ọrẹ, ẹbi ati alajọṣiṣẹ pọ wọn ni ọrọ ipinlẹ Ogun jẹ lọkan. O si da mi loju pe laarin ara wa owo ipolongo yoo yọju’’
Bẹẹ lo tun pẹlu idaniloju pe oun ṣi ni oludije gomina to koju osuwọn, to le sakoso ilu daadaa laarin awọn yooku ti wọn jọ dije.
No comments:
Post a Comment