Mo ti gbaradi fun ipolongo iṣejọba tuntun fawọn eeyan ipinlẹ Ogun- Ṣowumi - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 3 September 2022

Mo ti gbaradi fun ipolongo iṣejọba tuntun fawọn eeyan ipinlẹ Ogun- Ṣowumi


Ọtunba Ṣẹgun Ṣowumi, ikọ oludije fun ipo gomina fẹgbẹ oṣelu PDP, nipinlẹ Ogun, ti sọ pe bo tilẹ jẹ pe ipolongo fun eto idibo ko nii pẹ bẹrẹ amọ, oun ti gbaradi fun eyi ti yoo mu iṣejọba rere wa fawọn araalu.

Ọkunrin naa sọrọ yii nibi atẹjade kan to fi sita, o sọ pe ko si awitunwi asan mọ gbogbo awọn araalu lo ti mọ pe ipolongo ko ni pẹ bẹrẹ mọ tawọn ẹgbẹ oṣelu kọọkan yoo maa sọ nnkan ti wọn yoo ṣe fun wọn ti wọn ba wọle, o ni ki wọn gba akiyesi ki wọn ma ba a tun tan wọn jẹ lakooko yii.

Oludije gomina ọhun tun sọ pe igbaradi oun fun iṣejọba fawọn eeyan ipinlẹ Ogun lo wa lori ẹmi oun, nitori oun mọ bi ibo ọdun 2023, ṣe ṣe pataki .

O waa rọ awọn araalu lati gbọ nnkan tawọn ẹgbẹ oṣelu kọọkan ba sọ nitori oun ni yoo jẹ atẹgun fun wọn lati mọ ẹni ti wọn yoo ba dibo fun. Gẹgẹ bo ṣe wi,akoko naa kii ṣe fawọn oludije lati maa jo tabi kọrin bi ko ṣe lati jẹ ki araalu mọ ohun ti wọn ni lọkan.

Ṣowumi tun fikun ọrọ ẹ pe lara awọn nnkan tawọn gbọdọ gbaradi fun latọdọ awọn araalu ni wiwa idahun sawọn ibeere to nii ṣe pẹlu idagbasoke orileede, aabo atawọn nnkan mi-in to nii ṣe pẹlu idagbasoke.

O ni’’ Mo mọ pe awọn eeyan ti ṣetan lati fẹẹ gbọ nnkan tuntun latọdọ awa oloṣelu, ti mo si ti gbaradi, mo si lero pe ile-ẹjọ yoo ṣe awọn nnkan to yẹ lakooko’

Bẹẹ lo sọ pe inu oun dun sawọn iroyin toun gba nipa papakọ ofurufu ti wọn pe ni  Ogun Cargo, ati bi Gomina Dapọ Abiọdun ko ṣe jẹ ki ireti pin lori ẹ.

O waa ṣeleri pe papakọ Cargo yii jẹ ọkan lara erongba oun toun ba di gomina lọdun 2023.

O dupẹ lọwọ Gomina Abiọdun ati ẹni to gba ipo naa lọwọ ẹ, Sẹnetọ Ibikunle Amosun, lori bi wọn ṣe mu idagbasoke ba a pẹlu

 


No comments:

Post a Comment

Pages