Adebutu ti n lulẹ bọ, wọn ni ko si nibi ipade ti atiku bawọn oludije goima ṣe l’ Abuja - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 3 September 2022

Adebutu ti n lulẹ bọ, wọn ni ko si nibi ipade ti atiku bawọn oludije goima ṣe l’ Abuja


Afaimọ ki wahala to n waye ninu ẹgbẹ oṣelu PDP, ipinlẹ Ogun, maa ṣakoba fun wọn ninu ibo gomina to n bọ lọdun 2023, nitori awọn nnkan to waye labẹlẹ ninu ẹgbẹ naa.

Gẹgẹ bi iroyin ta a gbọ, wọn ni ọkan lara oludije fun ipo gomina naa nipinlẹ Ogun, Ladi Adebutu, ko si nibi ipade kan ti oludije wọn fun ipo aarẹ, Atiku Abubakar, pe gbogbo awọn gomina ti wọn dije labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP pe ni Abuja.

Ipade ọhun to waye loni in, ni wọn sọ pe Atiku ti bawọn oludije ọhun sọrọ lori igbesẹ ti wọn fẹẹ gbe lati le jẹ ki wọn jawe olubori ninu ibo to n bọ lọdun 2023.

Ninu ọrọ kan ti Atiku kọ sita, to ka bayii’’Lonii, mo ṣe ipade pọ pẹlu awọn oludije gomina PDP, nile mi niluu Abuja, lati jọ jiroro lori ọna ta o gba lati jẹ kawọn ọmọ orileede yii ṣiṣẹ pọ pẹlu wa’’

A o ranti pe awọn oludije meji lo jade lọtọọtọ nibi ibo abẹle fun ipo gomina, bi Ṣẹgun Ṣowumi, ṣe ṣe ti igun tiẹ ni iwe iroyin bẹẹ naa ni Adebutu atawọn mejeeji naa ṣe ti wọn ni Olusegun Obasanjo Presidential Library (OOPL) ni Abeokuta.


No comments:

Post a Comment

Pages