Emi ni yoo jẹ oludije gomina PDP Ogun nigbẹyin - Ọtunba Ṣẹgun Ṣowunmi - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Wednesday 7 September 2022

Emi ni yoo jẹ oludije gomina PDP Ogun nigbẹyin - Ọtunba Ṣẹgun Ṣowunmi


 

Ọtunba Ṣẹgun Ṣowunmi, ọkan lara oludije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu PDP, nipinlẹ Ogun, ti sọ pe  ahesọ lasan ni pe ẹgbẹ naa ti fọnka, wọn ti pin si oriṣiriṣi igun, o ni ko si nnkan to jọ bẹẹ nitori ọkan naa ni gbogbo wọn. Ati pe oun gbagbọ pe  oun loun yoo jẹ oludije fun ipo ọhun nigbẹyin.

 Ọkunrin naa sọrọ yii niluu Eko, O sọ pelu idaniloju pe  gbogbo ọmọ ẹgbẹ ni yoo ṣiṣẹ pọ fẹni to ba jawe olubori nibi igbẹjọ ile- ẹjọ to n lọ lọwọ ọhun, to si loun ni ifọkanbalẹ lee lori.

O ni pẹlu bi ile ẹjọ ko tẹmilọrun ṣe paṣẹ pe ki ile- ẹjọ giga to kọkọ da ẹjọ ẹ nu maa ba igbẹjọ naa, ti fihan pe didun lọsan yoo so foun nigbẹyin. Bẹẹ lo tun sọ pe ipolongo fun ipo gomina ọhun yoo bẹrẹ ni pẹrẹu lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu kẹsan-an, ni ọna ara.

Ṣowunmi ṣalaye pe ọna akọtun ti yoo tun ipinlẹ Ogun ṣe loun fẹẹ gbe ipolongo oun gba, ti yoo si jẹ ki ayipada de ba wọn, iyẹn ti wọn ba dibo yan oun wọle lọdun 2023.

 

Nigba to n sọrọ nipa  aṣilo agbara lati ẹgbẹ lapapọ ati tipinlẹ,  sọ pe ibo abẹle to gbe Ladi Adebutu wọle kii ṣe eyi to ṣe e tẹwọgba.

O sọ pe '' Ṣe ẹ ri ẹgbẹ oṣelu jẹ idasilẹ ofn, eyi to fun oloṣelu lagbara lati ja fẹtọọ ẹ, to si tun wa ninu ofin orileede wa pẹlu. Ni ero temi, ko si nnkan to jẹ ipinya, gbogbo la a gba nnkan ti ile-ẹjọ ba sọ, ṣugbọn mo si duro lori ibo abẹle ti wọn sọ pe awọn ṣe pe ko tọna, mi o si le gba''

O sọ pe ibo to gbe oun wọle gẹgẹ bi oludije tẹle gbogbo ilana ti  ofin orileede yii la kalẹ, kawọn eeyan ṣa foju sọna, o ni o da oun loju pe ayọ ni abajade idajọ naa yoo jẹ foun.

 

No comments:

Post a Comment

Pages