Ọnarebu Harrison Adeyẹmi, to n dije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu African Action Congress (AAC), nipinlẹ Ogun, ti sọ pe akoko ti ti fawọn ọdọ lati ma ṣe ta ọjọ ọla wọn fawọn ti ko ni mọ iyi.
Ati pe ẹgbẹ oṣelu AAC jẹ eyi to n kọya fun ọjọ iwaju awọn araalu tawọn ọmọ wọn pẹlu, nitori awọn ko nii fi ẹtan wọnu nnkan ti wọn ba n ṣe.
Oludije ọhun sọrọ yii nigba to ṣabẹwo lọ sọdọ Ojotumoro ilu Abigi,Ọba Oluṣẹgun Ogunye, fun ti ayẹyẹ ọdun karun-un ti ọba ọhun gori itẹ.
O ni gbogbo awọn eeyan ipinlẹ Ogun lo ti mọ pe ko si iyatọ ninu ọmọ aja ẹgbẹ oṣelu APC ati PDP, ti wọn ti ṣakoso nipinlẹ naa. O ni ijakulẹ ni wọn ti muu wa amọ ti opin gbọdọ de ba lakooko yii.
Adeyẹmi ṣalaye siwaju pe awọn ẹgbẹ oṣelu mejeeji yii ti danu, ti wọn si ti lulẹ pẹlu, idi niyii tawọn araalu ṣe gbọdọ fi ibo wọn gbe AAC wọlẹ fun ipo gomina, ninu ibo gomina to n bọ lọdun to nbọ yii.
O sọ pe ‘’ Ẹgbẹ wa ki i ṣẹgbẹ to wa alti tan araalu jẹ, mi o si fẹẹ ki ẹ gba awọn to ti n ja wa kulẹ lati bi ọdun meloo kan sẹyin lati tun rọwọ mu. Ti wọn yoo tun ko wa soko ẹru ọdun mẹrin mi-in. Ẹ dan ẹgbẹ ẹgbẹ AAC, ti a wa kọya wo, ki ẹ dibo yin fun mi fun ipo gomina Ogun yii, o si da mi loju pe ẹ ko nii kabamọ’’
O tun sọ pe igbe aye irọrun lawn yoo mu ba araalu, nitori o jẹ oun logun ju lọ.Bẹẹ ni aabo wọn tun ṣe pataki,ti yoo si yatọ si ainifọkanbalẹ tawọn to wa nibẹ mu bawọn.
O waa apri ọrọ ẹ pe iyanṣẹlodi awọn oṣiṣẹ fasiti (ASUU), jẹ eyi ti ko dara to, ko si ni ri bẹẹ lakooko tawọn ba de jọba.
No comments:
Post a Comment