Kọmureedi Abayọmi Olufẹmi Arabambi, to jẹ olupolongo fẹgbẹ oṣelu Lebọ lorileede yii ti sọ pe Ibikibi ti Ifagbemi Awamaradi ba ti pe ara ẹ ni oludije gomina fẹgbẹ oṣelu Lebọ ni Eko, awọn ọlọpaa yoo gbe, nitori ki i ṣe oludije awọn rara.
Ọkunrin naa sọrọ yii lakooko to n ba awọn oniroyin fọrọ- jo-mi- toro-ọrọ, nibi ti wọn ti fun Gbadebọ Rhodes Vivour, ni iwe ẹri gẹgẹ bi oludije gomina fun ẹgbẹ naa nibi ibo to n bọ, ti wọn si tun lo akoko naa lati fi ṣafihan awọn oloye tuntun, eyi ti Kayọde Salakọ jẹ alaga wọn.
Arabambi sọ pe Ifagbemi to pe ara ẹ ni Awamaridi ti kọkọ da ẹsẹ si ọdọ Ọlọrun naa, nitori Ọlọrun ọba nikan ni awamaridi, ati pe o ti kọwe fipo silẹ si ajọ INEC, pe oun ko dije mọ.
O sọ pe loootọ ni ọkunrin naa ti jẹ alaga fidihẹ fẹgbẹ oṣelu ọhun fawọn oṣu mẹta, mẹta kan, fun bi ọdun meloo kan ṣẹyin gẹgẹ bi ilana ofin nigba ti wọn ko tii dibo yan alaga tuntun.
O ni ṣe lọkunrin naa pe ara ẹ ni oludije gomina, to si ti lọ si ile- ẹjọ ṣugbọn tawọn ko ri igbesẹ kankan nibẹ.O ni gẹgẹ bi ero ọkan bi igba ti ọkunrin naa sọ ara ẹ di alawada adiẹ loun ka a si.
Arabambi tun sọ pe’’ Niwọgba ti a ti yan awọn oloye tuntun ninu ẹgbẹ yii ti wọn yoo maa tukọ, ko si ẹnu awamaridi nibẹ mọ. O wa sọ pe ọrọ yii ki i ṣe awada ibi ti Ifagbemi ba ti pe ara ẹ ni oludije gomina, awọn ọlọpaa yoo gbe, yoo si tun foju winna ofin.
Lẹyin to sọrọ tan, lo fun oludije wọn, Gbadebọ Rhodes Vivour, ni iwe ẹri lorukọ alaga ẹgbẹ naa lapapọ. Bakan naa lo darukọ awọn oloye ẹgbẹ tuntun fẹgbẹ oṣelu Lebọ nipinlẹ Eko.
Lara awọn oloye ọhun ni Kayọde Salakọ, to jẹ alaga wọn, Oloye Ṣeyi Ṣowunmi, igbekeji ẹ,Onimọ ẹrọ Adeọla Adebanjọ, toun naa tun jẹ igbakeji, Okpala Sam Emeka si ni akọwe ẹgbẹ naa, atawọn ogun mi-in.
Ninu ọrọ Gbadebọ Rhodes Vivour, o dupẹ lọwọ ẹgbẹ oṣelu Lebọ fun anfaani ti wọn fun un lati dije fun ipo gomina, o waa ṣeleri pe bi ogo ti n jẹ ti Ọlọrun awọn ni yoo jawe olubori ninu ibo to n bọ ọhun.
Bẹẹ lo sọ pe pẹlu awọn erogba oun toun ti ni lọkan, akoko ti to fawọn eeyan ipinlẹ Eko, lati kuro ninu oko ẹru, ti APC, Eko, ti ko wọn si lati bi ọdun meloo sẹyin. O wa bẹbẹ fun ifọwọsowọpọ awọn ọmọ ẹgbẹ naa lati jumọ ṣaseyọri , nitoti agbajọ ọwọ la fi n gbe ẹru dori.
No comments:
Post a Comment