Ọmọọba Rotimi Paṣẹda, oludije fun ipo gomina fẹgbẹ UPN ati SDP, nigba kan ri, ṣepade pọ pẹlu awọn alatilẹyin ẹ, lọsẹ to kọja, to si wọn lọkanbalẹ pe ibi tawọn ba n lọ ninu ibo to n bọ, oun yoo jẹ ki wọn gbọ.
Ṣugbọn ni bayii, ọkunrin naa ti sọ pe ko awitunwi asan kankan mọ oun atawọn ọmọ ẹyin oun ti gbaradi lati ṣiṣẹ fun Agbẹjọro Biyi Ọtẹgbẹyẹ, to n jade dupo gomina labẹ ẹgbẹ oṣeluADC, ninu ibo to n bọ lọdun 2023.
Paṣẹda kede ọrọ ọhun lakooko to n bawọn oniroyin sọrọ niluu Abẹokuta, lọjọ Aje, Monde, ana. O sọ pe oun kuro ninu ẹgbẹ APC, lati le jẹ ko ṣoro fun Gomina Dapọ Abiọdun lati le wọle ẹlẹẹkeji.
A o ranti pe inu ẹgbẹ oṣelu SDP, ni okunrin naa wa tẹ;ẹ ko to di pe o darapọ mọ APC. O ni ainiakasi Dapọ Abiọdun lo jẹ koun kuro ninu ẹgbẹ wọn ọhun, o wa ṣapejuwe ẹ gẹgẹ bi ọmọ alainiakasi niwaju Ọlọrun.
O wa sọ pe oun ti darapọ mọ ẹgbẹ oṣelu mọlẹbi,eyi ti Ibikunle Amosun,gomina tẹlẹ nipnlẹ Ogun jẹ aṣaaju ẹ.
Paṣẹda tun fikun ọrọ ẹ pe ‘’ Mo fi ẹgbẹ oṣelu APC silẹ, ki i ṣe pe wọn ṣe laburu amọ lati rii mo sagbara mi ki Dapọ Abiọdun, ko ma pada wa, Akiyesi mi nipa ẹ ni pe ko gbaradi fun ipo gomina to wa rara.
O ni bi oun ṣe kuro ni APC, oun ko kede pe oun lọ sinu ẹgbẹ oṣelu mi-in, oun ko si ni lero lati ṣe bẹẹ pẹlu. Amọ sa, oun pinnu lati fatilẹyin oun hamn si Biyi Ọtẹgbẹyẹ.
O ṣalaye siwaju pe ‘’ Bo tilẹ jẹ pe mi o si ninu oṣelu kankan ṣugbọn gbogbo nnkan to ba jẹ ti Rotimi Paṣeda nipinlẹ Ogun, lo maa jẹ ti Biyi Ọtẹgbẹyi., Nnkan mi-in to tun wa ni nibẹ ni pe apa kan Yewa, apa kan Ijẹbu tun ni. Ko si si nnkan ti mo le ṣe ju ki n ṣiṣẹ pọ pẹlu ẹ.
No comments:
Post a Comment