Ọwọ́ iléeṣẹ́ aṣọ́bodè tẹ tírélà Dangote méjì tí wọ́n fi kó ìrẹsì fàyàwọ́ wọ̀lú - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 28 August 2022

Ọwọ́ iléeṣẹ́ aṣọ́bodè tẹ tírélà Dangote méjì tí wọ́n fi kó ìrẹsì fàyàwọ́ wọ̀lú


 

 

Bi awọn aṣọbode ipinlẹ Ogun, ṣe n tiraka lati fopin si bi wọn ṣe n lo tirela Dangote, lati ma fi ko awọn irẹsi fayawọ wọlu,sibẹ wọn ko jawọ,bẹẹ ni aṣiiri wọn si n tu pẹlu.

 

Lọsẹ to kọja yii, ọga awọn aṣobode nipinlẹ naa, Bamidele Makinde, tun sọ pe irufẹ tirela meji yii lọwọ awọn tun tẹ to kun fun apo irẹsi.

 

Gẹgẹ bo ṣe wi, lakooko to n ṣe ipade pẹlu awọn oniroyin lori awọn aṣeyọri ti wọn ṣe laarin oṣu kan sẹyin, o sọ pe ibi meji lọwọ ti tẹ awọn tirela naa, eyi ti apapọ irẹsi ti wọn ko jẹ ọọdunrun le mẹta.

O sọ pe ‘’ Tirela kan ti nọmba ẹ jẹ EKY 971 YE , to jẹ ti ileeṣẹ Dangote, lọwọ tẹ lọna Ibese, nijọba ibilẹ Yewa North,lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkanlelogun, oṣu, kẹjọ, ṣe ni mọto ọhun kun fun apo irẹsi, ẹni to ba kọkọ ri mọto ọhun lọọkan yoo roo pe simẹnti ni wọn ko sibẹ’’

Bakan naa la tun gbọ pe ọwọ tẹ tirọọki ileeṣẹ yii ti nọmba ẹ jẹ BcH531 XA, toun naa kun fun apo irẹsi. Bẹẹ lo tun sọ pe lara awọn nnkan mi-in tawọn tun gba lọwọ awọn fayawọ ni oṣu to kọja ni aṣọ aloku ti wọn tun ta,ọkada mẹfa, asọ imulode,ọti waini, taya atawọn nnkan mi-in.

Ọga aṣọbode naa tun fikun ninu ọrọ ẹ pe miliọnu mẹtala lawọn ri ko jọ laarin oṣu kan fawọn nnkan atunta tawọn ta. O wa lo akoko naa lati fi kilọ fawọn araalu lati yẹra fawọn to n ṣe fayawọ fi ṣe yii, awọn ẹnikẹni tawọn ba gbọ pe o mu awọn eeyan ọhun sabẹ yoo foju winna ofin ijọba.

Makinde lawọn ṣetan lati fọwọsowọpọ pẹlu awọn araalu nipa okoowo wọn, ni eyi ti ni mu wahala dani tawọn naa yoo fi ni ifọkanbalẹ.

 

Bakan naa lo tun dupẹ lọwọ awọn ẹlẹkajẹka ẹsọ alaabo fun ifọwọsowọpọ ti wọn ni pẹlu wọn lati jọ gbogun tawọn ọbayejẹ eeyan, ti wọn fi ti wọn ṣakoba fun eto ọrọ aje orileede yii.

Capt;

 

 


No comments:

Post a Comment

Pages