Ariyanjiyan kan lo waye, lọjọ Iṣẹgun, Tusudee, ọsẹ yii ni ọfiisi Gomina, to wa ni Abẹokuta, laarin awọn ọmọ lẹyin ẹgbẹ oṣelu APC, ti wọn jọ n fa ọrọ naa laarin ara wọn.
Ọkan lo beeere lọwọ ẹnikeji ẹ pe, ṣe o gbọ pe Biyi Ọtẹgbẹyẹ, ti jade patapata lati dupo gomina, labẹ ẹgbẹ oṣelu ADC, nigba ti ẹnikeji yoo dahun, o ni rara, APM ni.
Niyẹn ba da a lohun pe ADC ni jare, nitori nigba tawọn ti gbọ, tawọn si ri bi nnkan ṣe n lọ, lọkan awọn ko ti balẹ mọ, nitori awọn ko mọ aayo to fẹẹ gbe wa, koda ọkan olori oko gan-an ko balẹ mọ.
Bẹẹ lọrọ naa ṣe n lọọ laarin awọn mejeeji. Iwadii fi ye wa pe gbogbo ọna ni wọn ko fẹẹ ki Biyi Ọtẹgbẹyẹ, jade dupo nitori wọn ti mọ pe ewu nla, lọkunrin naa yoo jẹ fun wọn.
Ati pe iṣoro ni yoo jẹ fun wọn lati ri ibo Yewa/ Awori mu ninu ibo to n bọ lọna, awọn yẹn o ṣaa le fi ọmọ wọn silẹ, ki wọn dibo fọmọ ibo mi-in, ẹ gbọ na, ta ni nnkan rere ko wu.
Idi niyii to fi jẹ pe lati ibẹrẹ pẹpẹ ni Dapọ Abiọdun, atawọn eeyan ti n gbogun lati ma jẹ ki wọn fawọn yooku ti wọn jọ dupo gomina nigba naa rọwọ mu, ninu ibo abẹle to kọja.
Ṣugbọn nigba ti Ọlọrun fẹẹ fi ara ẹ han, eedi di awọn to n ka ibo lọjọ naa, wọn si kede pe Ọtẹgbẹyẹ ni ibo kan, amọ loju ẹsẹ ni wọn tun fagile ibo ọhun, ti wọn ko si sọ idi pato titi di akoko yii.
Ohun to si faa ni pe ibẹru ọkunrin Yewa, to tun jẹ agbẹjọro lo n bawọn, nitori ti nnkan ko ba ri bi wọn ṣe n fẹ nigba naa, wọn le gbe fun un, idi niyii ti wọn fagile ibo kan ṣoṣo ọhun.
Ṣugbọn awọn kọ mọ pe oṣelu ti ju bi wọn ṣe fi si lọ, ero ọkan wọn si ni pe bawọn ko baa fawọn eeyan Gomina Amosun laaye, lati rọwọ mu ninu ẹgbẹ oṣelu APC, o tan niyẹn.
Gẹgẹ bi a tun ṣe gbọ, awọn eeyan yii ko tun dẹyin, nigba ti wọn fgbọ firi pe APM, ni Ọtẹgbẹyẹ tun ti fẹẹ jade dupo, ṣe ni wọn sọ pe, wọn tun lọ di ọna ibẹ, laimọ pe Ọlọrun ju ẹda lọ.
Gbogbo ero ọkan wọn si ni pe PDP, ni gbogbo awọn eeyan Amosun yoo lọ, eyi to fi wọn lọkanbalẹ pe ko sibi ti ẹgbẹ ọhun lọ, nitori ẹjọ wọn to wa nile-ẹjọ, ti ko sẹni to le sọ pato ibi ti yoo si, nitori ẹ ni wọn ko ṣe ri ti ẹgbẹ naa.
Bi wọn ṣe wa gbọ pe Biyi Ọtẹgbẹyẹ ti jade, la gbọ pe wọn ko nisinmi, ipade wọnu ipade ni wọn sọ pe wọn n ṣe,lati wa ọna abayọ ṣugbọn ti wọn ni wọn ko ri, ohun to daju ni pe Dapọ Abiọdun atawọn eeyan ẹ ko balẹ, bi wọn ko ṣe ni lulẹ ni wọn n wa bayii.
Ko si bi won ti fe se, won ti lule already.
ReplyDelete