Ipo gomina temi ki i ṣe fun ti okiki- Adeyẹmi Harrison - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Sunday 18 September 2022

Ipo gomina temi ki i ṣe fun ti okiki- Adeyẹmi Harrison


Adeyẹmi Harrison, oludije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu AAC, ti sọ pe okiki kọ lo fẹ mu oun dije fun ipo ọhun ti ibo rẹ yoo waye lọdun 2023, bi ko ṣe lati fi mu idẹrun ba araalu ati lati ṣe awọn nnkan to tọ to si yẹ.

Lọjọbọ, Tọsidee, ijẹrin ni ọkunrin naa sọrọ yii niluu Ijẹbu Ode, o ni nnkan to ṣe pataki toun si polongo ẹ kaakiri ni pe awọn eeyan gbọdọ kuro ninu inira tawọn ijọba to wa lode ko wọn si.

Bẹẹ lo tun sọ nita gbangba pe bi wọn ba le dibo yan oun wọle ninu ibo ọhun ẹkọ yoo di nnkan ọfẹ fun gbogbo ọmọ yunifasiti nipinle Ogun patapata. O ni oun ko tori atilowo, tabi agbara tabi okiki  gbegba oṣelu, bi ko ṣe lati sin awọn araalu lọna to tọ ati eyi to yẹ.

Hsrrison tun ṣalaye pe ” Oni kọ ni mo ti n ṣe awọn iṣẹ idagbasoke lawọn ibi kan nipinlẹ yii, ma a ṣe ju bẹẹ lọ ti mo ba di gomina. Ohun to ṣe koko lọkan mi ti mo fi n dupo yii ni lati mu ayipada rere ba ipinlẹ Ogun, fun idagbasoke orilẹ-ede Naijiria si ni.”

O fikun ọrọ ẹ pe  idajọ ododo ati ṣiṣe deede jẹ nnkan Pataki to yẹ ki o ṣe pataki lorieede yii, idi si niyi  to fi jẹ pe toun ba depo naa ìṣẹ́, oṣi ati airiṣẹ ṣe yoo dopin nipinlẹ Ogun.

O tun sọ pe’’ Mo mu da yin loju pe ọrọ aje ipinlẹ Ogun yoo ru gọgọ sí i ti mo ba fi le di gomina, emi nikan si kọ, emi atawọn ìkọ mi ti a ba jọ ṣejọba ni yoo ṣeto lori eyi. Bo tilẹ jẹ pe iṣoro to n koju ipinlẹ yii pọ gan-an, sibẹ  maa gbiyanju agbara mi.

Ninu ọrọ alaga ẹgbẹ AAC, nipinẹ Ogun, Ọgbẹni Adeṣina Afọlabi, sọ pe inu awọn dun bo ṣe waaa bawọn sọrọ ati pe ile nile ẹ. O ni ẹni to kaju ẹ to si ṣee dibo fún ni Ọmọọba Harrison Adeyẹmi.


No comments:

Post a Comment

Pages