Biyi Ọtẹgbẹyẹ dẹru jẹjẹ si APC ipinlẹ Ogun lọrun - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Saturday 17 September 2022

Biyi Ọtẹgbẹyẹ dẹru jẹjẹ si APC ipinlẹ Ogun lọrun


Titi di akoko yii ni jinnijinni ṣi n de ba awọn ẹgbẹ oṣelu kan nipinlẹ Ogun paapaa julọ APC ati PDP, ohun to si n fa a koju pe ariwo pe Agbẹjọro Biyi Ọtẹgbẹyẹ, ti mura silẹ lati dije fun ipo gomina ninu ibo to n bọ lọdun 2023.

Ohun to si n jẹ ki ibẹrubojo mu wọn ni pe wọn ko mọ ọna ti ọkunrin naa fẹẹ gba ati pe ariwo pe o jade dupo labẹ ẹgbẹ oṣelu ADC, ni wọn n gbọ, amọ oun gan-an funra ẹ ko tii jade sita bawọn eeyan sọrọ.

Iwadii fi ye wa pe bi ala lọrọ ẹ si n jẹ fawọn ẹgbẹ oṣelu APC, nitori erongba wọn ni pe nigba tawọn ti fun ọkunrin naa pa ninu ẹgbẹ naa nigba to kọkọ jade dupo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu ọhun, awọn yoo ro pe yoo gba kamu ni.

Ati pe  gbogbo nnkan ti wọn sọ labẹlẹ to han sita gbangba ni pe nigba ti Ọnarebu Adekunle Akinlade, ti lọ si ẹgbẹ oṣelu PDP, nibi ti wọn ti fun un ni tikẹẹti igbakeji gomina, boya Ọtẹgbẹyẹ naa yoo gba tikẹẹti sẹnetọ, amọ ti  wọn ko mọ pe ero ọkunrin naa yatọ gedegbe si ti wọn.

Oniroyin wa tun fidi ẹ mulẹ pe gbogbo ọna ni ẹgbẹ oṣelu APC n gba bayii lati fi tun fdi ọna mọ Ọtẹgbẹyẹ,  bi wọn ṣe ṣe fun Akinlade ti wọn gbe lọ sile-ẹjọ lati ma ṣe jẹ ki oun ati Ladi Adebutu jade dupo, ni wọn tun sa labẹlẹ amọ, ti wọn ni Ọlọrun ko fun wọn ṣe.

Kaka bẹẹ ṣe ni wọn sọ pe ẹgbẹ oṣelu ADC, ti ọkunrin naa ti jade dupo ti n fi ojoojumọ pọ si, tawọn naa ko si dakẹ ipade lori bi oludije wọn yoo ṣe jawe olubori ninu ibo ọhun. Ariwo tawọn kan si n pa ni pe aṣẹ ti Sẹnetọ Amosun ba pa fawọn lawọn yoo mulo lori ibo to n bọ yii.

Bẹẹ ni wọn si ti mọ pe ko sibo mii-in ti Amosun ti fẹẹ ṣiṣẹ bayii bi ko ṣe ẹgbẹ oṣelu ADC, nitori bi wọn ṣe ti n ri ami ọwọ ẹ nibẹ, bẹẹ la tun gbọ pe ọjọ kẹrin, oṣu to n bọ lawọn kan ṣi n duro de nigba ti ajọ INEC, yoo gbe orukọ awọn oludije gomina ati igbakeji wọn jade.

Wọn ni akoko yii ni ẹgbẹ oṣelu APC ipinlẹ Ogun yoo ṣẹṣẹ waa ri idan ti wọn ko tii ri, nitori igba naa lawọn ti eeyan yoo wa jade sita lati jẹ ki wọn mọ pe ADC lawọn, gbogbo awọn nnkan yii ni wọn sọ pe o n da jinnijinni bo APC, ti ọkan Dapọ Abiọdun ko balẹ mọ.

Bi awọn araalu ba si le tẹle awọn ipinnu ti wọn ṣe labẹle o ṣee ṣe ki APC fidi janlẹ nipinlẹ Ogun, nitori awọn araalu pariwo ijọba wọn ti su wọn, ti ọrọ ba si ri bayii, ADC, lawọn eeyan yoo fẹẹ dibo fun, nitori titi di akoko yii ọrọ PDP, ko tii ye ara wọn, wọn ẹsẹ Ladi Adebutu si n mi nibẹ. 


No comments:

Post a Comment

Pages