Lọsẹ to kọja yii, ni wọn ṣe ifilọlẹ ẹgbẹ kan ti wọn pe ni Ọọni Peace Movement , OPM, ti ẹka ipinlẹ Ọyọ, to waye niluu Ibadan. Nibi eto ọhun lawọn ọba alaye atawọn eeyan jakejado kaakiri orileede yii ti peju pesẹ.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, Ọọni tiluu Ile-Ifẹ, Ọba Adeyẹye Ẹnitan Ogunwusi, lo ṣagbekalẹ ẹgbẹ naa fun ogo ilẹ Yoruba ati lati jẹ ki alaafia jọba kaakiri. Latigba ti wọn si ti daa silẹ ni Biṣọọbu Biṣọọbu Ezekiel Ọlasunbade Olukunle JP, to jẹ alakoso ẹgbẹ ọhun ti bẹrẹ si tan an kaakiri de ọdọ awọn ọba alaye,to si ṣalaye idi ti wọn fi da a silẹ.
Ọpọ ibi ti wọn si n de la gbọ pe wọn ti n gba wọn ni tọwọ tẹsẹ, tawọn naa si n sọ pe ẹgbẹ OPM, yii ki i ṣe nnkan tio ẹnikan le da a ṣe, awọn gbọdọ gbarukutu ti wọn ni. Ayẹyẹ ọhun to waye niluu Ibadan ni Ọba Adebisi Adenikawoṣẹgun Layade, Alara Ondaye tilẹ Ara, ni Ifẹ, ti waa ṣoju Ọọni lọjọ naa pẹlu awọn Oloye to tẹle e wa.
Ninu ọrọ Biṣọọbu Ezekiel Ọlasunbade Olukunle JP, to jẹ alakoso ẹgbẹ ọhun lorileede yii lo ti sọ pe ninu oṣu kẹfa, ọdun yii lawọn ẹgbẹ ọhun dide fun ogo ilẹ Yoruba. Bẹẹ lo tun ni awọn ṣagbekalẹ ẹ lati fi da igbimọ apapọ ti yoo wa fun alaafia ilẹ Yoruba silẹ.
O sọ pe latigba tawọn ti daa silẹ lawọn ti n tan kaakiri ilẹ Yoruba ati kaakiri ni orileede yii, awọn to jẹ pe erongba wọn jọ ni i ṣe pẹlu ogo ilẹ ọhun ati pe bi Ọba Adeyeye Ẹnitan Ogunwusi, ṣe fẹẹ ko ri bẹẹ naa lori. O waa ṣeleri pe awọn tun ti n gbero lati ṣe ifilọlẹ ẹgbẹ naa lawọn ipinlẹ yooku.
Nigba toun naa sọrọ nibi ayẹyẹ yii, Ọba Adebisi Adenikawoṣẹgun Layade, Alara Ondaye tilẹ Ara, to ṣoju Ọọni Ifẹ, sọ pe Kabiyesi ni ki oun dupẹ lọwọ gbogbo awọn to wa nibẹ. Ati pe ki wọn jẹ ki ogo ilẹ Yoruba ṣe pataki nibi ti wọn ba wa.
Ọba naa sọ pe oun kan patakt to maa n dun Ọọni lọkan ni ki gbogbo ọmọ ilẹ Yoruba wa ni alaafia, ki wọn fimọ sọkan ki wọn ma si ṣe gba ọtẹ laaye, o ni o jẹ ọkan lara nnkan ti wọn ṣe palaṣẹ fun Biṣọọbu lati da ẹgbẹ yii silẹ.
Kabiyesi tun fikun ọrọ ẹ pe ‘’OPM, ẹgbẹ ti wọn da silẹ fun isọkan Yoruba ati ilọsiwaju, ki i ṣe ti ẹlẹyamẹya, bẹẹ ni ki i ṣe ti oṣelu, ẹgbẹ ti Baba wa Ọọni tile-ifẹ da silẹ ni. Ogo Yoruba, awọn ogo wa to fẹẹ ma ṣọnu, ki a gba a pada, ki gbogbo awọn ọba, ki wọn fimọ sọkan, ki ogo yẹn le jẹ mimulo’’.
Ṣugbọn Ambasedọ Mary Odunayọ Ilegbemi, to jẹ akọwe agba ẹgbẹ OPM, sọ ni tiẹ pe fun ọmọ bibi ilẹ Yoruba, lo wa fun ,ki iya ma ba jẹ ọmọ Yoruba, ki ifẹ le wa laarin wọn. Lọjọ naa ni wọn tun fawọn ọmọ ẹgbẹ tuntun ni fọọmu lati darapọ mọ wọn.
No comments:
Post a Comment