Awon ogbontarigi oloselu omo egbe APC darapo mo ADC ni Atan-Ijebu - BO SE RI

Breaking

Coco Samba

Coco Samba
Coco Samba

Tuesday 20 September 2022

Awon ogbontarigi oloselu omo egbe APC darapo mo ADC ni Atan-IjebuPelu idunnu ati ayo ni alaga fegbe oselu ADC ni Atan-Ijebu, nijoba ibile Ijebu North East, nipinle Ogun, se gba ogunlogo ojulowo awon omo egbe oselu APC, sinu egbe won.

Nibi ipade won to waye lana-an ni won ti ki awon eeyan ohun sinu egbe tuntun yii pelu ileri pe won too jo sise po fun ibo odun 2023.

Iwadii fi ye wa pe ko to to akoko yii ni awon ipade lorisirisi ti waye, eyi to wa so eso rere bayii.

Onarebu Osimade, Onarebu Onafuye,Onarebu Adegbuyi ati Onarebu Toyin Onademuren, lọ saaju awon omo egbe APC wa darapo mo egbe tuntun yii.

A tun gbo pe bawon ogbontarigi oloselu yii se bo sinu egbe oselu tuntun yii je adanu nla fun egbe APC, nitori iriri ati Oro won ninu oselu. 

Bakan naa ni Onarebu Onedemuren to ti figba kan je asofin nile igbimo asofin ipinle Ogun fun ekun naa laaarin odun 2011 si 2015, amo to tun fee jade leekeji labe egbe oselu ADC fi idunnu e han bi won se gba won towo tese. Pelu ileri pe won too jo sise po.

Bee ni okunrin yii tun lo anfaani naa lati lati fa Ile kan kale fun omo egbe fun igbaradi won fun ibo to n bo lona naa ati bo se je pe agbegbe naa ni won ti bi iya Agbejoro Biyi Otegbeye, oludije gomina labe egbe oselu ADC.
  Odoopotu- Ijebu  ati Iworo- Ijebu  ni won so pe iya naa ti wa.

No comments:

Post a Comment

Pages